Owó tí mo fẹ́ fi rán Faith lọ fásítì ni mo fi sin òkú rẹ̀ - Bàbá ọmọbìnrin tó "pa ara rẹ̀" torí èsì ìdánwò JAMB

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Opesusi Oluwafemi to jẹ Baba ọmọdebinrin to gba ẹmi ara rẹ lẹyin to wo esi idanwo Jamb to ṣe ti sọ pe owo toun fẹ lọ lati ran Faith Opesusi lọ ile ẹkọ giga fasiti ni oun fi sin oku rẹ

Ọgbẹni Opesusi sọrọ yii ninu ifọrọwanilẹnuwo ti o ṣe pẹlu ileeṣẹ amohunmaworan Channels TV.

Faith Opesusi, ẹni ọdun mọkandinlogun lo ni erongba lati lọ ka imọ nipa Microbiology ni fasiti ṣugbọn awọn erongba yii ni ko le wa si imusẹ mọ lẹyin igbesẹ to gbe nigba to wo esi idanwo Jamb.

Oloogbe yii jẹ ọkan ninu ọpọ ọdọ to kopa ninu idanwo Jamb ti ọdun 2025.

Ajọ JAMB si ti jade sita lati sọ pe otitọ ni pe awọn ṣe ọpọ aṣiṣe nipa esi idanwo naa eyi to fa ti ọpọ akẹkọọ se fidi rẹmi.

Baba Faith sọ ninu ifọrọwanilẹnuwo to ṣe wi pe ajọ JAMB ko tii kan si oun lori iku ọmọdebinrin rẹ titi di akoko yii.

Bakan naa ni Ọgbẹni Opesusi tun sọ pe ko si aṣoju ijọba kankan to tii kan soun bakan naa lori iku ọmọ oun.

''Ohun ti mo n beere lọwọ ajọ JAMB ni pe ki wọn sọ fun mi maaki ti ọmọ mi gba gan an ninu idanwo to ṣe.

Ọmọ mi gba maaki nla lọdun to kọja ninu idanwo Jamb, ni ọdun yii wọn fun ni maaki mẹrindinlaadọjọ, 146, ibanujẹ ọkan lo fa a, to fi gba ẹmi ara rẹ.

Kii ṣe esi idanwo ti ajọ JAMB funra rẹ sọ pe aṣiṣe wa nibẹ ni mo n beere fun un.

Esi idanwo Faith gan an gan an ni mo fẹ, bi bẹẹ kọọ, Ọlọrun a dajọ o.

Mo mọ pe esi idanwo yii ko le da ọmọ mi pada, ṣugbọn nnkan to beere lọwọ mi niyẹn ki o to ku,'' Ọgbẹni Opesusi lo sọ bẹẹ.

Baba oloogbe naa ṣapejuwe Faith gẹgẹ bi ọmọ to mọ iwe rẹ to si tun jẹ onirẹlẹ eeyan.

Ọgbẹni Opesusi ni bi ọmọ oun ṣe kọju mọ ẹkọ rẹ ni o tun n kọ iṣẹ onidiri bakan naa.

Koda, o ni ọpọ awọn Ọjọgbọn olukọni ni fasiti LASUSTECH lo maa n ṣe irun fun nigba aye rẹ.

"Esi idanwo UTME ti ajọ JAMB gbe jade ni orukọ ọmọ mi, ki i ṣe esi idanwo ti ọmọ mi gba"

Opesusi, baba oloogbe ba BBC sọrọ ṣaaju pe esi idanwo UTME ti ajọ JAMB gbe jade ni orukọ ọmọ oun, ki i ṣe esi idanwo ti ọmọ oun gba.

"Awọn ọmọ ode isinyii ni wọn tete ma banujẹ, ọrọ naa ba ọmọ mi lọkan jẹ pupọ bi o ṣe ri esi idanwo naa" Baba sọrọ.

Gẹgẹ bii Baba naa ṣe sọ, o ni ka ni ọmọ naa sọ ẹdun ọkan rẹ sita ni, awọn yoo ti gbe igbesẹ lati bu omi tutu si lọkan.

Opesusi ni o dun oun pupọ pe ọmọ naa gba ẹmi ara rẹ.

Ẹgbọn Faith Opesusi salaye iru eeyan to jẹ nigba aye rẹ

Ẹgbọn oloogbe, Opeyemi Opesusi ṣapejuwe oloogbe gẹgẹ bii eeyan to fara siṣẹ, to si tun ni iwa irẹlẹ.

"Nigba to bẹrẹ si ni maa bi, mo bi i pe kin lo se e, to si sọ fun mi pe oun ti jẹ majele.

"Ile iwosan lo ti sọ fun mi, to si mi kanlẹ."

Ikorodu nipinlẹ Eko Faith n gbe pẹlu ẹgbọn rẹ, nigba ti iṣẹlẹ naa waye.

Ẹgbọn oloogbe ni Faith ri ile ẹkọ wọ ọdun to kọja ṣugbọn nitori pe ile ẹkọ naa jinna, ni ko se lọ si ile ẹkọ naa.

O ni o fẹ wa ni ile ẹkọ kan naa pẹlu awọn ẹgbọn rẹ lobinrin.

"A wa mẹjọ la wa ninu ẹbi wa ṣugbọn bayii a ti dinku si meje".