Ìbálòpọ̀ akọ sí akọ, abo sí abo di ìwà ọ̀daràn ni Iraq

Oríṣun àwòrán, Getty image
Ni bayii, wọn ti ka ibalopọ akọ si akọ ati abo si abo bii iwa ọdaran lorilẹ-ede Iraq.
Igbimọ aṣofin Iran lo gbe aba kan jade to n kede ajọṣepọ yii bi iwa ọdaran.
Ẹwọn ọdun mẹwaa si mẹẹẹdogun ni wọn ni ẹni tọwọ ba tẹ yoo fi jura labẹ aba tuntun yii.
Bakan naa ni awọn akọ ti wọn n sọ ara wọn di obinrin, ati obinrin to n ṣe bii ọkunrin naa le fi ẹwọn ọdun kan si mẹta jura bọwọ ba tẹ wọn.
Awọn to faramọ aba yii ti ni ohun ti yoo ran ẹsin awọn lọwọ ni.
Ṣugbọn awọn ajafẹtọọ ọmọniyan sọ pe afikun ni aba naa jẹ nipa bi Iran ṣe n tẹ ẹtọ awọn eeyan mọlẹ.
Wọn ni ofin ti ko fẹran akọ to n ṣe bi abo, ati abo to n ṣe bi akọ ni.
Awọn aṣẹwo, dokita to n pa akọ da si abo ati awọn ti wọn n ṣe paṣi-paarọ iyawo yoo lọ ẹwọn labẹ aba yii pẹlu.
Àbá tó léwu tó sì lè dààmú ọkàn lèyí’
Akọwe ijọba UK, David Cameron, sọ pe aba to lewu to si le daamu ọkan eeyan ni Iraq da yii.
Cameron kọ ọ soju opo X rẹ pe, ’’ko yẹ ka maa dajusọ ẹnikẹni nitori iru eeyan ti wọn jẹ.
" A rọ ijọba Iraq lati mu ẹtọ ọmọniyan ni koko, ki wọn si faaye gba awọn eeyan lai yan ẹnikan laayo tabi daju sọ ẹnikẹni’’
Bo tilẹ jẹ pe Iraq sọ pe oun gbe aba yii kalẹ lati dẹkun awọn iṣesi to tako ẹsin Islam ni, ko si tun le dẹkun iwakiwa, sibẹ, orilẹ-ede Amẹrika naa ta ko o.
Amẹrika sọ pe aba to n dunkooko mọ ẹtọ ọmọniyan ni.
Wọn ni yoo si tun ṣakoba fun ọrọ aje ilu naa.
Awọn arinrin ajo ko ni i maa wa sibẹ lati wo wọn bi wọn ṣe sọ.














