Mọ̀ síi nípa àwọn igbákejì gómìnà lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí wón ti yọ nípò

Mọ nípa àwọn igbákejì gómìnà lorilede Naijiria tí wón yóò nípò

Lẹyin ti Ile aṣofin Oyo kede ìgbesẹ wọn lati yoo igbakeji gomina kuro nípò, latari bi wọn se fi ẹsun marun un ọtọtọ kan Onimoero, Rauf Olaniyan.

BBC News Yoruba se akojọpo awọn igbakeji gomina lorilede Naijira ti wọn ti sagbako iyiyo nipo lati ọdun 1999.

Oloye Iyiola Omisore

Oloye Iyiola Omisore, igbakeji gomina ipinlẹ Osun ni ẹni akoko ti o jẹ igbakeji gomina ti awọn ọmọ ile gbimo asofin ipinlẹ yoo kuro nipo lẹyin ti wọn ti fe ẹsun kan pẹ ko tẹlẹ adehun ti o se nigba ti o bo si ipo.

Omisore lo jẹ igbakeji fun Gomina Bisi Akande.

Dokita Chris Ekpenyong

Dokita Chris Ekpenyong ni igbakeji gomina ipinlẹ Akwa ibom lọdun 2005, ti awọn ile gbimo asofin yoo nipo latari ti ija waye laarin oun ati gomina ipinlé naa nigba naa Victor Attah

Abiodun Aluko

Awọn ọmọ ile gbimo fi ẹsun kan Dokita Ekpenyong pẹ ko kpta ninu ayẹyẹ odun awarawa ati pẹ o lo ipo rẹ lati gba isẹ agbasẹ fun ileese rẹ.

Labẹ isakoso ijọba Ayo Fayose lọdun 2005, igbakeji Abiodun Aluko ni awón ile gbimo asofin fe ẹsun merindinlogun kan, ti wọn si yoo nipo gege bi gomina. Ile gbimo asofin ipinlẹ Ekiti ni Abiodun Aluko jẹbi ẹsun naa.

Otunba Olufemi Pedro

Lẹyin ti Asiwaju Bola Ahmed Tinubu kede Babatunde Fashola gege bi Oludije gomina ti o fowo si, Otunba Olufemi Pedro, to jẹ igbakeji gomina ko faramo ikede naa, ti o si tẹ oko lẹti lọ si ninu ẹgbẹ oselu, Labour Party lati jide dupo Gomina lọdun 2007

Lẹyin idibo ọdun 2007, Otunba Olufemi Pedro ko iwe fi ipo sile sugbon Gomina Tinubu ati awọn ile gbimo asofin si da iwe naa pada.

Ojo keji ni awón ọmọ ile gbimo asofin kede pé awón ti yo Otunba Olufemi Pedri nipo.

Sani Abubakar

Iyoo nipo Sani Abubakar, igbakeji gomina Taraba ni o mu ọpọlọpọ ariyanjiyan lẹyin ti o fi ẹsun kan Gomina Danbaba Suntai pẹ o gbe owo toto ẹgberun milonu fun awọn ọmọ ile gbimo asofin lati yoo nipo.

Abubakar ni wọn fi ẹsun aṣilo ipo igbákejì gómìnà.

Mahdi Gusau.

Igbakeji Gomina ipinlẹ Zamfara, Mahdi Gasau ni o iyiyoo nipo rẹ waye lẹyin o ko lati tẹlẹ Gomina Bello Matawalle lọ si ninu ẹgbẹ oselu All Progressive Congress lati ninu ẹgbẹ oselu People’s Democratic Party.

Kete ti Gomina Matawalle darapo mo ẹgbẹ oselu APC NI ni awọn ọmọ ile gbimo asofin yoo igbakeji Mahdi Gusau nipo.