Ìdílé MKO Abiola ló borí lọ́dún 1993, A tún máa borí lọ́dún 2023- Kola Ọmọ MKO Abiola

Oludije fun ipo aarẹ labe asia ẹgbẹ oselu Peoples Redemption Party, Kola Abiola ti ni ohun jewe olubori ninu eto idibo to n bo lọdun 2023 gege bi baba rẹ, Oloye MKO Abiola sẹ bori lọdun 1993.

Abiola ni o sọrọ yii niluu Abuja lẹyin o gba iwe ijẹrisi gege bi oludije fun ipo aarẹ lọdun 2023 lọwọ alaga fun ẹgbẹ oselu Peoples Redemption Party, Falalu Bello.

O ni darapo mo ẹgbẹ oselu Peoples Redemption Party nitori eto ijọba tuntun ti ẹgbẹ fe fi sita fun awọn ọmọ orilede Naijira

O tẹsiaju ninu oro rẹ lati gba awọn ọdo niyanju pẹ ọpọlọpọ atunse lo gbodo ti ọwo ọdo nitori pẹ awọn ọdo lo gbarukudi baba oun lọdun 1993.

“Ọgbon ọdun sẹyin. A jaweolubori ninu ẹto idibo Aarẹ, mo de mọ pẹ atunlẹ fowosowopo gege bi ase sẹ ni lọdun naa pẹlu baba mi ni ọdun 2023.

“Mo fe ro awọn ọdo lati mọ pẹ ki ayipada le wa ni orilede Naijira, a gbodo fowosowopo ati bori ninu ẹto idibo to n bo lọdun 2023

“Ti a ba le se lọdun 1993, a le tunse lọdun 2023.’”