You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọ̀pọ̀ ọkọ̀ akẹ́rù wọlé sí Gaza bí Israel àti Hamas ṣe dáwọ́ ìjà dúró fọ́jọ́ mẹ́rin
Ọpọlọpọ mọto akẹru to ko awọn ohun eelo isegun, epo bẹntiroolu ati ounjẹ lo ti morile agbegbe Gaza bayii lati ilẹ Egypt.
Igbesẹ naa waye lẹyin ti Israel ati Hamas se adehun lati dawọ ogun duro fun ọjọ mẹrin gbako.
Ijọba ilẹ Quatar lo se agbatẹru adehun igbesẹ alaafia naa, ti ajọ eleto ipese ounjẹ lagbaye si ni o le ni ọgọrun ọkọ akẹrun to ti setan lati gbe ounjẹ lọ si agbegbe Gaza.
Orilẹede Egypt ti seto ẹgbẹrun lọna aadoje lita epo disu ati ọkọ akẹru mẹrin fun afẹfẹ gaasi eyi ti yoo gbe wọ Gaza lonii.
Igba àkọ́kọ́ ree ti Hamas ati Israel yoo gba alaafia laaye lati ọ̀sẹ̀ meje ti ogun ti bẹ̀rẹ̀
Saaju ni orilẹede Israel ati ikọ Hamas fẹnuko lati dawọ ogun duro fun ọjọ mẹrin.
Ti o ba jẹ aṣeyọri, eyi yoo jẹ idaduro ogun akọkọ ti yoo waye lati bi ọsẹ meje ti ogun naa ti bẹrẹ.
Adehun idaduro ranpẹ yii pẹlu itusilẹ awọn adọtaa obinrin ati ọmọde to jẹ diẹ lara awọn eeyan ogojilenigba ti ikọ Hamas ji gbe lasiko ikọlu ọjọ keje oṣu kẹwaa.
A n reti pe ki awọn eeyan mẹtala to wa ni ipele akọkọ gba itusilẹ ni dede ago mẹrin lonii.
Bakan naa, orilẹede Israel yoo tu awọn ọmọ orilẹede Palestine aadọjọ ti wọn jẹ obinrin ati ọmọde to wa ahamọ silẹ
Israel ni ogun ko tii pari
Idaduro yii yoo tun mu ki itura de ba awọn eeyan Palestine ti wọn le ni milọnu meji to wa ni Gaza pẹlu ileri pe awọn ohun iranwọ yoo wọle ti wọn pẹlu adehun ijọba wọn tọwọ bọ.
Israel ti jẹ ko di mimọ pe ogun ko ti pari, ijọba Israel ti se ileri lati ri awọn ọna yanju gbogbo mu ọmọ ikọ Hamas, ti wọn da awọn ẹlẹwọn pada.
Hamas, ikọ ti US ati orilẹede agbaye mii sapejuwe Hamas gẹgẹ bi ikọ agbebọn.
O ni adehun yii yoo mu Palestine ni anfani lati wo egbo ti Israel da si wọn lara nipasẹ ado oloro oju ofurufu.
Awọn alakoso Palestine ni awọn ado iku yii lo ti ṣekupa o le ni ẹgbẹrun mẹrinla eeyan ni Gaza.
Wo kókó àdéhùn tí Israel àti Hamas ṣe láti dáwọ́ ìkọlù dúró
Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe orílẹ̀ èdè Israel àti ikọ̀ Hamas ti fẹnukò lórí àwọn àdéhùn kan láti ṣe ìdádúró ìkọlù tí wọ́n ń ṣe sí ara wọn fún òjò mẹ́rin.
Israel àti Hamas fẹnukò pé àádọ́ta nínú àwọn ọmọ Israel tó wà ní àhámọ́ Gaza ni wọ́n máa tú sílẹ̀ àti pé kò ní sí ìkọlù sí ara wọn fún ọjọ́ mẹ́rin tí ìtúsílẹ̀ náà ma fi wáyé.
Tí àdéhùn yìí bá kẹ́sẹ járí, èyí ló máa jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ tí wọ́n máa ṣe ìdádúró ìkọlù láti ìgbà tí ogun ti bẹ̀rẹ̀ láàárín wọn.
Isreal fẹ ki Hamas tu eeyan 50 to wa nigbekun silẹ, Hamas n beere idande eeyan 150
Àwọn aláṣẹ Israel ní èèyàn àádọ́ta tó fi mọ́ àwọn obìnrin àti ọmọdé ni Hamas ma tú sílẹ̀.
Ṣíṣe ìdádúró ìkọlù ló máa wáyé fún ọjọ́ mẹ́rin ní ó sì ṣeéṣe kó ju bẹ́ẹ̀ lọ fún ọjọ́ kan.
Wọ́n ní ènìyàn mẹ́wàá tí Hamas bá tú sílẹ̀ ni wọ́n yóò fi gba ọjọ́ kan ní èyí tó túmọ̀ sí pé tí wọ́n bá tú èèyàn sílẹ̀ si ju àádọ́ta lọ, ó ṣeéṣe kí ọjọ́ tí wọn yóò fi ṣe ìdádúró ìkọlù àlékún si.
Israel ṣàlàyé pé ìdádúró ìkọlù ní àwọn àsìkò yìí kò túmọ̀ pé ogun ti parí láàárín àwọn, wọ́n ní àwọn bá ti tú gbogbo àwọn ènìyàn sílẹ̀ ná ogun yóò tẹ̀síwájú títí tí àwọn máa fi rẹ́yìn ikọ̀ Hamas pátápátá.
Bákan náà ni wọ́n fi kun pé tí àwọn bá ti rí àrídájú rẹ̀ pé ìkọlù kankan kò lè wáyé láti Gaza mọ́ sí Israel ni ogun tó máa sinmi.
Hamas ní tirẹ̀ ní àádọ́jọ àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Palestine, tó fi mọ́ àwọn obìnrin àti ọmọdé tó wà ní àhámọ́ Israel ni wọ́n máa tú sílẹ̀ fún àwọn.
Orílẹ̀ èdè Qatar to ṣe agbátẹrù bí àdéhùn náà ṣe wáyé ní àwọn ọkọ̀ tó kó ohun ìrànwọ́, oúnjẹ àti epo bẹntiróòlù ni wọ́n máa fún láàyè láti wọ Gaza lásìkò tí wọ́n bá fi dáwọ́ ìkọlù dúró.
Human Rights Watch ní ó lé ní ẹgbẹ̀rún méje ọmọ Palestine tó wà ní àhámọ́ Israel
Israel ti fi ọ̀ọ́dúnrún orúkọ àwọn ọmọ Palestine tí wọ́n fẹ́ tú sílẹ̀ léde.
Orúkọ náà tó wà ní ìtàkùn àgbáyé ilé iṣẹ́ ètò ìdájọ́ Israel ṣàfihàn orúkọ, ọjọ́ orí àti ẹ̀sùn tí wọ́n mú wọn fún.
274 nínú àwọn 300 ọ̀hún ló jẹ́ ọkùnrin tí àwọn yòókù sì jẹ́ obìnrin.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wọn kò ì tíì fi ìgbà tí dídáwọ́ ogun dúró ná yìí yóò bẹ̀rẹ̀, Qatar ní ó ṣeéṣe kí wọ́n kéde ìgbà tí yóò bẹ̀rẹ̀ láàárín wákàtí mẹ́rìnlélógún.
Ṣáájú ni àjọ tó ń jà fún ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn, Human Rights Watch ní, ó lé ní ẹgbẹ̀rún méje àwọn ọmọ Palestine tó wà ní àhámọ́ Israel.
Wọ́n ní àwọn obìnrin tí iye wọn tó igba àtàwọn ọmọdé ọgọ́ta ló wà nínú wọn.
Wọ́n ní lára ẹ̀sùn tí wọ́n fi fi àwọn ọmọ náà sí àhámọ́ ni sísọ òkò.