Obasanjo, ìlànà ìjọba alágbádá tí o fisílẹ̀ là ń tẹ̀lé, ọ̀rọ̀ kò dùn lẹ́nu rẹ - Iléeṣẹ́ ààrẹ

Ileeṣẹ aarẹ Naijiria lo ti dẹbi ipo ti ijọba awaarawa wa nilẹ yii ru aarẹ tẹlẹ ri, Olusegun Obasanjo.

Oludamọran fun Aarẹ Bola Tinubu lori eto iroyin, Bayo Onanuga lo fesi fun Obasanjo lori bo ṣe juwe oṣelu awaarawa bii ohun ti ko ṣe anfaani fun ọpọ ọmọ Naijiria ati Africa lapapọ.

Aarẹ tẹlẹ ri naa lo sọrọ nibi ipade apero kan nilu Abeokuta to da lori iṣatunro ijọba awaarawa nile adulawo.

"Obasanjo gbe ilana isejọba kalẹ nigba to jẹ aarẹ ologun laarin ọdun 1976 si 1979"

Onanuga tẹsiwaju pe Obasanjo lo pe fun atunto iṣejọba nilana ti yoo ba aṣa ati iṣe ilẹ adulawọ mu, ti yoo si ṣe ogunlọgọ awọn araalu lanfani ju awọn perete ti wọn n jẹ mudunmudun ijọba awaarawa bayi.

Onanuga ninu ọrọ rẹ woye pe, Obasanjo ko lẹtọ lati sọ ohunkohun nipa ilana ijọba ni Naijiria nitori pe oun gan lo ṣe idasilẹ ilana ti a n lo lọwọ yii.

O ni ilana naa lo gbe kalẹ nigba to jẹ aarẹ ologun laarin ọdun 1976 si 1979, to si tun tẹsiwaju bii aarẹ alagbada laarin ọdun 1999 si 2003.

Olubadamọran aarẹ naa wi pe “o yẹ ki Obasanjo ranti pe oun lo ṣe ifilọlẹ ilana ti a n lo yii lọdun 1979.

O yẹ ko ti rii pe ko ba wa mu ati pe o n na wa lowo gọbọi nigba to jẹ aarẹ labẹ ijọba awaarawa fun ọdun mẹjọ, amọ n ṣe lo n wa bi yoo ṣe ṣe ọdun mẹrin miran sii."

"Bi Obasanjọ ṣe n sọrọ yii, o da bii pe o ṣẹṣẹ n lọgbọn lori lẹyin to kuro lori aleefa ni"

Bayo Onanuga ni “Bi Obasanjọ ṣe n sọrọ yii, o da bii pe o ṣẹṣẹ n lọgbọn lori lẹyin to kuro lori aleefa ni.

“Ijọba awaarawa nilana tawọn Gẹẹsi fi silẹ fun wa la n ṣe, ki awọn ologun to gbajọba lọdun 1966.

Nigba ta fẹ pada sijọba alagbada lọdun 1979, n ṣe ni Obasanjo lọ ya ilana ilẹ America gẹgẹ bi imọran awọn kan, to si mọ pe eleyi maa na wa lowo ju ilana ilẹ Gẹẹsi ti a nlo tẹle lọ."

Onanuga tun bu ẹnu atẹ lu bi Obasanjo ṣe ya ilana isejọba ilẹ America eyi to ni ko kunju iwọn to.

“Koda, Obasanjọ mọ pe ọna odi ni oun gba wo awokọṣe ilana ilẹ America nitori pe afiwe ilana nikan lo wo, ko woye ifarajin ati ifẹmiti ti wọn fi n ṣe e.

“Eyi to tun yẹ ko se atunṣe rẹ laarin ọdun 1999 si 2003 to pada di aarẹ alagbada, amọ igbiyanju ati yi ofin pada, ko le ṣe saa kẹta lo n ba kiri.”

Ìjọba àwaarawa àwọn òyinbó tí à ń tẹ̀lé l’Áfíríkà kò ṣiṣẹ́ fún wa - Obasanjo

Aarẹ orilẹede Naijiria tẹlẹ ri, Oloye Olusegun Obasanjo ti sọ pe ijọba awaarawa awọn oyinbo ti ilẹ Afirika n tẹle ko ṣiṣẹ fun Afirika.

Obasanjo to sọrọ yii ninu ọrọ apilẹkọ rẹ to sọ nibi apero kan ti wọn pe akọri rẹ ni ijiroro lori ‘’ẹda ijọba awaarawa awọn oyinbo fun ilẹ Afirika’’ eyi to waye ni ile ikawe Olusegun Obasanjo Presidential Library niluu Abeokuta lọjọ Aje.

Obasanjo ni ijọba awaarawa awọn oyinbo ko ṣiṣẹ fun Afirika tori irufẹ ijọba yii ko ka ero ọpọ eeyan kun.

Aarẹ Naijiria tẹlẹ ri sọ pe tipa tipa ni wọn fi ṣe agbekalẹ ijọba awaarawa nilẹ Afirika eleyii ti ko jẹ ko ṣiṣẹ.

Nigba ti o sọ nipa ijọba awaarawa ti ilẹ Afirika, Obasanjo ni ‘’ijọba awaarawa awọn oyinbo jẹ ijọba eeyan perete lori ọgọrọ eeyan, ati awọn eeyan perete yii ki i ṣe aṣoju ọpọ araalu.

Nitori naa, ogunlọgọ eeyan ni ijọba awaarawa ko ni ipa kankan lori wọn.

Awọn ti wọn pe e ni ijọba ọpọ eeyan, ṣe o le jẹ ijọba ọpọ eeyan ki eeyan naa ma mọ ohun to n ṣẹlẹ ninu ijọba ọhun?

A ko mọ ipilẹsẹ irufẹ ijọba awaarawa yii, a ko mọ bi wọn ṣe sẹe, a kan n loo lọ bẹẹ naa ni, bo tilẹ jẹ pe a mọ pe ko ṣiṣẹ fun wa.

Koko irufẹ ijọba k’ijọba ni lati mojuto igbayegbadun awọn araalu.

A gbọdọ da iwa aṣiwere wa duro, ki a si fi opin sii.

A ni lati pe ara wa si ajọ to ni ironu ki a wo orilẹee wa, aṣa wa ati iṣe wa fun ọpọlọpọ ọdun ki a si sẹ agbekalẹ irufẹ ijọba to le ṣiṣẹ fun wa.’’

Aarẹ Naijiria tẹlẹ ko tọ kawọn orilẹede Afirika maa tẹle irufẹ ijọba ti wọn ko mọ nkan kan nipa ipilẹsẹ ati agbekalẹ rẹ.