Ilé alájà mẹ́rin dà wó l’Ábújá, èèyàn mẹ́ta farapa

Aworan ile to dawo

Oríṣun àwòrán, Others

Bo tilẹ jẹ pe eeyan kankan ko ku nibi ile alaja mẹrin kan ti wọn n tun kọ niluu Abuja to si dawo lọjọ Aje, ọjọ kin-in-ni oṣu keje 2024 yii, sibẹ, awọn mẹta gba ibẹ de ileewosan latari ifarapa.

Agbegbe banki IBTC to wa ni Area 11 ni ile to dawo naa wa gẹgẹ bi ọga awọn panapana l’Abuja, Amiola Adebayo, ṣe ṣalaye.

O ni nnkan bii aago mẹsan-an ku ogun iṣẹju lalẹ ni ijamba naa waye lọjọ Mọnde yii.

Adebayọ ṣalaye pe ile atijọ to ti pẹ ni ile ọhun, o ni wọn n ṣe atunkọ ati atunṣe rẹ lọwọ lati sọ ọ di tigbalode ni ijamba ṣẹlẹ.

Bi ile naa ṣe wo lo mu mẹta lara awọn ti wọn n ṣiṣẹ nibẹ farapa, ti wọn si sare gbe wọn lọ sile iwosan lẹyin ti wọn yọ awọn eeyan mi-in ti wọn tun wa nibẹ jade.

Josephine Adeh, Agbẹnusọ ọlọpaa niluu Abuja naa fidi iṣẹlẹ yii mulẹ.

O ni awọn ti fi to ẹka to n ri si iṣẹlẹ pajawiri leti, awọn oṣiṣẹ wọn si ti gbe igbesẹ to yẹ.