Kílódé tí ẹnu ń kun Seyi Makinde lórí ìpolongo ìbò tí Peter Obi fẹ́ ṣe ní'badan lónìí?

Aworan

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde

L'aipẹ yii ni ariwo Gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọẹrọ Ṣeyi Makinde gba ode kan, paapaa julọ lori opo ikansiraẹni Twitter, lori ipolongo ibo oludije si ipo aarẹ orilẹede Naijiria ninu ẹgbẹ oṣelu 'Labour Party', Peter Obi.

Abẹwo ti BBC Yoruba ṣe si oju opo ikansiraẹni naa lo fi idi rẹ mulẹ wipe niṣe ni awọn eeyan n gbe oṣuba kare fun Makinde nitori anfani ti o fun Obi lati ṣe ipolongo idibo ni papa iṣere Lekan Salami to n bẹ ni Adamasingba niluu Ibadan, pẹlu bi o ṣe jẹ pe awọn mejeeji ko si ninu ẹgbẹ oṣelu kan naa.

Saaju asiko yii ni Peter Obi ti ṣe ipolongo ibo ni awon ipinlẹ kan, sugbọn ti awọn Gomina ipinlẹ naa ko fun un ni aye lati lo ibi ti o wuu.

Ọkan lara awọn ipinlẹ naa ni ipinlẹ Edo, nibi ti Godwin Obaseki ti jẹ Gomina.

Papa iṣere Samuel Ogbemudia ni egbe oṣelu Labour Party gbero lati lo tẹle, sugbọn Obaseki ni oun ko fun wọn ni anfani lati lo ibẹ nitori o pe ki wọn to fi ọrọ naa to ijọba leti.

O ni gbogbo igbaradi ati atunṣe ti o ye ki ijọba ṣe ni papa iṣere naa ni ko si aye fun, nitori pe lojiji ni wọn beere fun anfani lati lo papa iṣere naa.

Bakan naa ni ile ẹjọ kan nilu Eko ti paṣẹ saaju wi pe awọn alatilẹyin Obi ko gbudọ kora jọpọ ni ẹnu iloro 'Lekki Toll Gat' lati ṣe iwọde tabi ipolongo ibo fun Peter Obi.

Igbese ti Makinde gbe lati fun ẹgbẹ oṣelu naa ni anfani n'ipinlẹ Ọyọ, lo jẹ nnkan iyalẹnu ti o si mu ki ọpọ eeyan maa fọn rere rẹ lori ayelujara.

L'Ọjọru ni ipolongo ibo naa yoo waye ni papa iṣere to n bẹ ni Adamasingba.

Papa iṣere naa ni aye ti o le gba ẹgbẹrun mewaa eeyan lẹẹkan ṣoṣo.