Wo oore mẹ́fà tí Cucumber lè ṣe fún ara rẹ bí o bá ń jẹ ẹ́

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ohun jijẹ to kari ọja kaakiri orilẹede Naijiria ni Cucumber, ko ṣoro lati ri rara.

Awọn onimọ nipa ounjẹ to ṣe atupalẹ eroja to wa ninu cucumber, ṣalaye pe o ni awọn fitamin bii: Vitamin A, K, C ati awọn eroja bii potassium, calcium ati fiber.

Eyi ni awọn anfaani ilera ti ẹni to ba n jẹ cucumber yoo maa ri lara rẹ, gẹgẹ bi awọn dokita onimọ nipa ounjẹ ṣe fidi ẹ mulẹ.

Fún àdínkù itọ ṣuga

Ọpọ iwadii lo ti fidi ẹ mulẹ, pe bi eeyan ba n jẹ cucumber, o maa n mu adinku ba apọju ṣuga ninu ara.

Bakan naa lo maa n dena awọn ewu to rọ mọ itọ ṣuga.

Idi niyẹn ti cucumber fi maa n wa lara ounjẹ ti awọn dokita maa n ni ki ẹni to ba ni itọ ṣuga maa jẹ.

Dokita Lilian Felix to ṣalaye eyi, tẹsiwaju pe:

"Eyi ri bẹẹ nitori eroja fiber pọ ninu cucumber, eroja naa lo maa n ri i daju pe ṣuga ko ga si i ninu ẹjẹ."

2. Fún ara àsanjù

Cucumber jẹ ounjẹ kan to le mu ara sisan dinku, idi eyi ni pe eroja calory inu rẹ ko pọ.

Dokita Lilian Felix ṣalaye pe, "ọkan ninu awọn ounjẹ ti a maa n ni kawọn to ba sanra maa jẹ ni, lati din ara sisan naa ku."

3. Cucumber maa ń dènà kí ara gbẹ:

Pataki ni omi nile aye yii, bi ko ba si omi, eeyan ko le yè.

Bi eeyan ba n jẹ cucumber, iwadii awọn dokita fi han pe o maa n ṣe iranwọ fun bi ẹjẹ ati awọn eroja yoku ṣe n rin kiri ara.

Wọn fi kun un pe o maa n jẹ ki ounjẹ tete da ninu pẹlu, o si daa fun kindinrin, o tun maa n jẹ ki ara tutu.

Gẹgẹ bi a ṣe mọ, omi pọ ninu cucumber,eyi to tumọ si pe ti o ba jẹ ẹ, omi yoo wa lara tirẹ naa.

Eso to tun farapẹ ẹ ni water melon.

Awọn onimọ nipa ounjẹ sọ pe ida marundinlaadọrun-un (95%) ohun to wa ninu cucumber jẹ omi.

"Igba mi-in wa ti awọn eeyan ko ni i mu omi to loju ọjọ, ṣugbọn bi eeyan ba le fi cucumber kun ounjẹ rẹ, yoo ran bo ṣe yẹ ki omi wa lara eeyan lọwọ."

Dokita Felix lo ṣalaye bẹẹ.

4. Fún ṣíṣe ìgbọ̀nsẹ̀ nírọ̀rùn

O daa fun ẹni ti ko ba ri igbọnsẹ ṣe nirọrun lati maa jẹ cucumber.

Idi ni pe omi ati eroja fiber to wa ninu cucumber yoo bẹrẹ iṣẹ ti igbọnsẹ naa yoo fi wa nirọrun.

5.Cucumber maa n jẹ ki ara jọ̀lọ̀

O máa ń mu ìfúnpá gíga wálẹ̀:

Bi awọn dokita ṣe ṣalaye, cucumber ni eroja potassium ninu, eyi to maa n din eroja ti a mọ si sodium ku ninu ara, ti ifunpa giga yoo si walẹ sipo to yẹ.

Apọju iyọ jijẹ lo n fa ki sodium pọ ninu ara.

Ìkìlọ̀ nípa jíjẹ Cucumber

Bi eeyan ko ba ni awọn iṣoro wọnyi ninu ara, awọn onimọ nipa ounjẹ gba wọn nimọran lati maa jẹ cucumber ẹyọkan pere lojumọ.

"Awọn eeyan to ba ni aisan inu bii ọgbẹ inu tabi ti ẹjẹ wọn maa n dì ko gbọdọ jẹ cucumber.

Afi bi dokita wọn tabi alabojuto ilera wọn ba n mojuto jijẹ ti wọn n jẹ ẹ naa."

Onimọ nipa ounjẹ, Lilian Felix lo kilọ bẹẹ.