''Ọ̀rẹ́kùnrin mi tẹ́lẹ̀ ń dààmú mi, ni mo ṣe lọ sójú òpó tó ní ààbò láti wá olólùfẹ́, àmọ́ àbámọ̀ lo gbẹ̀yìn ọ̀rọ̀ mi"

    • Author, Jacqui Wakefield
    • Role, Global Disinformation Unit, BBC World Service
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ọrẹkunrin Sally ko fi i silẹ bo tilẹ jẹ pe wọn ti yapa, ni ṣe ni ọrẹkunrin rẹ tẹlẹ yii tun maa n wa a lọ sibi iṣẹ tabi lọ sile awọn ọrẹ rẹ.

Nigba to ya ni Sally bẹrẹ si ni lo aapu kan tawọn obinrin ti le mọ nipa awọn ọrẹkunrin wọn ati sọ nipa awọn ọkunrin to dẹnu ifẹ kọ wọn.

Awọn ọdọbinrin to n lo ''Tea app'' lorilẹede Amẹrika to n maa n fawọn ololufẹ ni imọran le kegbare ti wọn ba ri pe ọkunrin to dẹnu ifẹ kọ wọn ti ṣe igbeyawo tabi ti o ba ti huwa ipa ibalopọ si ẹnikẹni ri.

Bakan naa lawọn obinrin tun le lo aapu yii lati mọ ọrẹkunrin to ba n dibọn.

O le ni eeyan miliọnu kan to n lo aapu yii ni Amẹrika.

Awọn ọkunrin to n tabuku obinrin n sọ nipa fọto awọn obinrin to tu sori ayelujara

BBC ti ṣawari oniruuru aapu ati itakun ayelujara tawọn fọto ati aṣiri awọn obinrin to wa lori ''tea app'' wa.

Ọkan lara iru awọn itakun ayelujara naa ṣe akojọpọ awọn fọto tawọn obinrin naa fi sori ''Tea App'' ti wọn si sọ fawọn eeyan wi pe ki wọn maa wo eyi to maa wu wọn.

Ọpọ eeyan lo n tabuku fọto awọn obinrin naa lori itakun ayelujara.

Ninu nnkan ti BBC ri, awọn eeyan n sọ oriṣiiriṣii nipa bawọn obinrin ṣe dun un wo si, bakan naa ni wọn n pin fọto wọn lai gbaṣẹ lọwọ wọn.

BBC ri isọri bii mẹwaa lori Telegram tawọn ọkunrin ti n sọ nipa awọn obinrin to wa lori ''tea app'' nibi ti wọn ti n lo awọn fọto ti wọn fi AI ṣe atọwọda rẹ ṣe gbọyi sọyi nipa awọn obinrin.

Agbẹnusọ Telegram sọ pe pinpin fọto ihoho ara eeyan lodi sofin, ati pe awọn yoo yọ iru fọto bẹẹ kuro tawọn ba ti ri i.

John Yanchunis, agbẹjọro to n ṣoju ọkan lara awọn obinrin naa ni ọpọ eeyan lo ti tabuku oun naa lori itakun ayelujara.

Ija laarin awọn obinrin ati ọkunrin

Ọpọ eeyan lo ti sọ pe fọto ati aṣiri awọn obinrin to tu sita ni ṣe pẹlu faakaja laarin awọn obinrin ati awọn ọkunrin.

Ẹri ti wa pe ọpọ awọn ọdọ ni wọn ko fẹ maa ni ọrẹkunrin tabi ọrẹbinrin fun igba pipẹ mọ.

Iwadii ti ajọ Pew ṣe lọdun 2023 l'Amẹrika fi han wi pe o le ni idaji awọn obinrin ti wọn ko ni iriri to dara lori aapu tawọn ololufẹ ti n pade.

Ọmọwe Jenny Van Hooff to jẹ onimọ nipa ihuwasi ẹda ni fasiti Manchester Metropolitan sọ pe aisi abo to to ni ipa lori bawọn ọdọbinrin ṣe n kopa ninu didọọrẹ lori ayelujara.

Hooff ṣalaye pe ''iriri ọpọ eeyan lori ayelujara jẹ ki wọn maa bẹru, iwa kawọn ọkunrin maa tabuku awọn obinrin n pọ si.''

Fun apẹẹrẹ, Hooff ni nigba ti ọpọ eeyan kọkọ gbọ nipa ''tea app,'' inu wọn kọkọ dun pe aapu naa yoo ru aṣiri awọn ọkunrin.

Amọ, gbogbo rẹ daru lẹyin tawọn kan ya bo aapu naa ti wọn si bẹrẹ si ni pin fọto awọn obinrin kaakiri ori ayelujara.

Bakan naa ni Hooff tun sọ pe ọpọ ninu awọn to n ṣagbekalẹ iru aapu fẹ fi pawo lasan an ni

Ọmọwe Hooff sọ pe ohun to ṣẹlẹ si ''tea app' tubọ fidi faakaja to wa laarin awọn obinrin atawọn ọkunrin mulẹ si i ni.

Awọn obinrin ko ri aabo ti wọn n wa, bakan naa lawọn ro pe awọn obinrin n fi aapu naa ṣofofo nipa awọn.

Fun Sally, bi aṣiri rẹ to wa lori ''tea app'' ṣe tu sita ti ṣakoba fun eto abo rẹ.