Mi ò lè bá ọba kankan jà ìjà àgbà, ìjọba Gẹ̀ẹ́sì gan-an gbà pé Alaafin làgbà ọba nílẹ̀ Yorùbá - Ọba Owoade

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ọrọ ija agba meji ti ọpọ eeyan gbagbọ pe o n waye laaarin Alaafin Oyo, Oba Abimbola Owoade ati Ooni Ife, Oba Adewoye Ogunwusi, ṣi n tẹsiwaju.

Idi ni pe lẹyin atẹjade ikilọ ti Alaafin Owoade fi sita, pe ki Ooni da oye to fun Dotun Sanusi, oniṣowo pataki ilẹ Ibadan pada, eyi ti Ooni ko fesi si ti wakati mejidinlaadọta ti Alaafin fun Ọọni fi pe, Oba Owoade tun ti fi atẹjade mi-in sita.

Ninu atẹjade Alaafin to jade l'Ojobo, ọjọ kọkanlelogun oṣu Kẹjọ ọdun 2025, ni Ọba Owoade ti ni oun ko nilo lati ba ọba kankan nilẹẹ Yoruba tabi nibikibi lagbaaye ja ija agba .

Alaafin ṣalaye pe ko ruju rara, pe Oba Oyo Alaafin ni agba ọba nilẹẹ Yoruba, nitori ijọba ilẹ Gẹẹsi gan-an mọ eyi, wọn si gba a bẹẹ ninu adehun.

"Ilẹ Gẹẹsi mọ bi agbara iran idile ọlọba ṣe to, lo ṣe tọwọ bọ iwe adehun to gbe Alaafin bori awọn ọba yoku nilẹ Yoruba"

Ni itẹsiwaju alaye Alaafin Owoade, ninu atẹjade ti Akọwe iroyin rẹ, Bode Durojaiye to kọ ti iṣaaju tun fi sita, wọn ni :

"Idi ti Alaafin ko fi nilo lati ba ọba kankan jija agba nilẹẹ Yoruba abi nibikibi lagbaaye, akọkọ ni pe Oyo di olokiki nipasẹ ọla ati agbara ikọ ologun rẹ.

Oun lo tobi ju ni gbogbo ilẹ Africa, oun si ni apaṣẹ-waa wọn.

"Pataki julọ, gẹgẹ bi ìṣe ilẹ Gẹẹsi, wọn mọ bi agbara iran idile ọlọba ṣe to, iyẹn ni wọn ṣe gba lati tọwọ bọ iwe adehun to gbe Alaafin bori awọn ọba yoku nilẹ Yoruba.

"Bakan naa, ọrọ manigbagbe ti onimọ ijinlẹ, Alexander Graham Bell, sọ pe awọn eeyan to ni laari ju nigbẹyin, ni awọn to jẹ eni tere, eji tere ni wọn fi ko aṣeyọri wọn jọ.

Eyi ri bẹẹ fun Alaafin Oyo.

"Ẹni to fẹsọ pilẹ ilọsiwaju rẹ nipele-ipele ni, to si ṣe bẹẹ gbooro to di nnkan nla, o di dandan ko yege.

Bẹẹ ni irinajo aye Alaafin Owoade, alagbara ọba to fẹ rere fun ẹda eeyan gbogbo ṣe ri.

" Alaafin funra ẹ ni olutọju aṣa ati iṣẹ Yoruba, ko si figba kankan yẹ nipa itọju naa ri.

"Ko tori ikoko asaro ta awọn ijoye ati awọn eeyan rẹ lọpọ ri.

Koda, itan gan-an foju ire wo Alaafin Owoade latigba to ti gun ori itẹ awọn Baba nla rẹ, nitori ko nilo lati ba ẹnikẹni jija agba kankan, yala nilẹẹ Yoruba tabi nibikibi laye.

"Alaafin to fi iwa irẹlẹ kun ọla oriade, to n fi iyi dari nilana igbalode asiko yii.

"Kabiyesi,ọba ti ẹni kan ko gbọdọ bi lẹjọ. Iku Baba Yeye; ẹni ti i paṣẹ fun iku, oun gan-an lo bi iku. Alashe Ikeji Orisha."

Bẹẹ ni apa kan atẹjade naa ṣalaye nipa titobi Alaafin gẹgẹ bi ọba.

''Alaafin Owoade ṣe àdéhùn pẹ̀lú Ifa, Sango àti àwọn òrìṣà mi-in láti ṣojú wọn láyé''

Ni itẹsiwaju alaye yii, atẹjade naa ka pe aṣoju awọn oriṣa bii Sango, Ifa ati bẹẹ bẹẹ lọ ni Alaafin Owoade lorilẹ aye.

Wọn ni eyi ri bẹẹ nitori Alaafin ṣe adehun lojubọ iṣẹmbaye ilẹ Yoruba, pe oun yoo maa gbeja, da aabo bo aṣa ati iṣe ilé Yoruba, oun yoo si ri i pe ẹwa aṣa Yoruba ko parun.

Wọn ko ṣai mẹnuba Oduduwa ati ọmọ-ọmọ rẹ ọkunrin, Oranmiyan.

Wọn ni Oduduwa lo bi Okanbi, Okanbi lo bi Oranmiyan, ko too kan awọn bii Ila-Orangun, Oni-Sabe, Olu-Popo, Ala-Ketu, Oba-Benin.

Atẹjade naa sọ pe wọn wa si Oyo nigba ti ọgbẹlẹ n ba Ile-Ife finra, ti awọn eeyan si n ṣi kuro nibẹ, ti wọn n fi Oyo ṣe ile wọn.

Pẹlu awọn alaye to fi ajulọ han yii, esi ti yoo ti Ife tabi apa ibomiran nilẹẹ Yoruba wa ni ọpọ eeyan n duro de.