Ta ni Frank Caprio "Adájọ́ tó ṣe ọmọlúàbí jùlọ lágbàáyé"?

    • Author, Yang Tian
    • Role, BBC News
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Frank Caprio, ilumọkaa adajọ ni Amẹrika ati irawọ nla loju opo ayelujara, ti ku ni ẹni ọdun mejidinlaadọrun, idile rẹ lo kede bẹẹ.

Lasiko ogoji ọdun to lo ni Rhode Island, o lo aanu ati awada lati ṣe idajọ.

Awọn fidio ti Adajọ Caprio ti n ṣakoso awọn ọran lori ifihan TV ti o kọlu "Caught in Providence" ni ọpọ wiwo lori ayelujara, ti wọn si fun ni oye "adajọ to dara julọ ni agbaye."

Iku rẹ waye to lugbadi aisan jẹjẹrẹ pancreatic, ti awọn mọlẹbi si kede ipapoda lori opo ayelujara Instagram rẹ.

"Adajọ Frank Caprio ku lai si irora kankan ni ọdun mejidinlaadọrun, lẹyin ọpọ ọdun to ti n ba aisan jẹjẹrẹ finra."

Ọpọ mọ ọ fun "iwa irẹlẹ ati "igbagbọ ti ko ni iyemeji ninu ṣiṣe eeyan oore."

Adajọ Caprio ṣe alakoso ọpọ igbẹjọ ni ilu abinibi rẹ, Providence, Rhode Island, ṣaaju ki o to bẹrẹ iṣẹ lori tẹlifisan.

Bi o ṣe n ṣe eto rẹ da yatọ, ti ọpọ fidio rẹ si wa kaakiri, bẹrẹ lati bi o se n kesi awọn ọmọde lati wa jokoo pẹlu rẹ lasiko igbẹjọ, ti yoo si pe wọn ni adajọ kekere.

Awọn fidio rẹ, eyi ti o lọ kaakiri ayelujara, ṣafihan adajọ to nifẹẹ ọmọniyan pupọ lasiko to ba n dojukọ awọn ẹlẹṣẹ ti wọn ni iṣoro owo.

Fidio TikTok kan ti o n ṣe ifihan iṣẹ-ṣiṣe owurọ rẹ — fifọ eyin rẹ, fọwọ́ si iwe rẹ, ati wiwo awọn fidio lati ori opo tirẹ — ti iye eeyan to si ti wo àwọn fídíò rẹ náà ti le ni milọnu marun un.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo 2019 kan, Adajọ Caprio sọ pe awọn igbẹjọ rẹ "ṣe afihan igbesi aye ni Rhode Island, ati awọn ọran ti ọpọ n koju kaakiri orilẹ-ede naa."

Ọmọkunrin rẹ, David Caprio, dupẹ lọwọ awọn ololufẹ rẹ fun ifẹ ati atilẹyin wọn, o wa rọ gbogbo eniyan lati "tan oore sise kaakiri" ni iranti baba rẹ.

Loju opo Instagram rẹ to ni awọn ọmọlẹyin 3.4m, Adajọ Caprio ni wọn gbe iyìn fun "awọn iṣe oore ainiye ti o gbe ṣe."

Atẹjade loju opo rẹ sọ pe: "Ifẹ rẹ, awada ati aanu rẹ fi alafo nla silẹ ninu i gbogbo awọn ti o mọ ọ."

Caught in Providence gba ọpọ ami ẹyẹ, pẹlu eyi adajọ Caprio funrararẹ gba meji ni ọdun to kọja.

Ileeṣẹ to n gbaruku ti, Debmar-Mercury, yìn Adajọ Caprio fun "anu alailẹgbẹ ati bi ko ṣe ki n gba igbakugba."

"A o se afẹri rẹ gan," awọn alaga Mort Marcus ati Ira Bernstein sọ ninu atẹjade kan.

Lẹyin to lugbadi aisan jẹjẹrẹ ni ọdun 2023, Adajọ Caprio sọ pe "o ti mura ni kikun lati ja pẹlu gbogbo agbara rẹ" o dupẹ lọwọ awọn ọmọlẹyin rẹ fun atilẹyin wọn.

Ninu ọkan ninu awọn ohun to gbe sita laipẹ, Adajọ Caprio kede ipadabọ rẹ si ile-iwosan lẹyin ti o ni iriri "idaduro" ninu itọju rẹ, to si sọ fun awọn ọmọlẹhin rẹ lati gbadura fun un.

Adajọ Caprio fi idile nla kan silẹ, iyawo rẹ ti o ti fẹrẹ to ọgọta ọdun, Joyce Caprio, ati awọn ọmọ wọn marun un, awọn ọmọ-ọmọ meje ati awọn ọmọ-ọmọ ọmọ meji.