Queen Elizabeth: Ọbabìnrin fi ìwé ìpè síta pẹ̀lú adé nígbà tó pé ọdún mẹ́fà

Ọbabinrin Elizabeth ati aburo rẹ, Margaret wa lori ẹsẹ awọn obi wọn

Oríṣun àwòrán, Universal History Archieve/Getty Images

Orí to ba máa dádé inú agogo idẹ ní í ti í wá, ọrùn tí yóò lo èjìgbà ìlẹ̀kẹ̀, inú agogo idẹ náà ní í ti í wá, orí tí yóò sì lo mọ́sàjiì, aṣọ ba tó jiná koro-koro, inú agogo idẹ náà ló ti ń wa.

Bakan naa, orí tí yóò jọba kò ní ṣàì jọba.

Onírúurú ọ̀rọ̀ ló ti máa ń jáde wí pé Ọba ìlú Òyìnbó, Queen Elizabeth, ní ìbẹ̀rẹ̀ ayé rẹ̀, pàápàá nígbà ọdún mẹ́wàá àkọ́kọ́, kò mọ̀ wí pé òun le jọba ilẹ Gẹẹsi.

Ó jẹ́ ọmọ tó jẹ́ pé lásìkò ìgbà náà, kò mọ̀ ju kó máa bá àwọn ẹṣin àti àwọn ajá rẹ̀ ṣeré, láì mọ̀ ohun tí ọjọ́ ọ̀la ní lákọ̀ọ́lẹ̀ fun.

Lónìí, ọjọ́ Àìkú ọjọ Kẹfa osu Keji ọdun 2022 ló pé àádọ́rin ọdún tí Elizabeth di Ọbabinrin fun ilẹ Gẹẹsi, to wa ni ìlú òyìnbó.

A lè fi wé ọmọọba Beatrice tó jẹ́ ọmọ Duke tí York lóde òní, tí ọ̀nà rẹ̀ jìn sí ipò ọba débi ti yóò lálàá wí pé òun yóò ṣe olórí fún àwọn tó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta mílíọ̀nù ènìyàn.

Báwo ni ìrìnàjò Ọba jíjẹ́ ṣe ṣí sílẹ̀ fún Elizabeth?

Ní ọdún 1936 ní ohun tí ó jọ pé ó ṣínà ọba jíjẹ fún Ọba Elizabeth ni nígbà tí ẹ̀gbọ́n bàbá rẹ̀, David tó jẹ́ Ọba Edward VIII ya gbogbo ayé àti mọ̀lẹ́bí rẹ̀ lẹ́nu nígbà tó fi ipò sílẹ̀ láti lọ fẹ́ Wallis Simpson, tó jẹ́ ará Amẹ́ríkà.

Ìgbésẹ̀ David yìí jẹ́ kí bàbá Elizabeth gba ipò ọba gẹgẹ bii ọba George VI, tí àkọ́bí ọmọ rẹ̀, tí í ṣe Elizabeth, sì di àrẹ̀mọ.

Iya Elizabeth gbe ọbabinrin lọwọ nigba to wa ni kekere

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ǹjẹ́ lóòótọ̀ ni pé Elizabeth kò mọ̀ pé òun yóò jẹ ọba tàbí gbáradì fún ipò náà?

"Bàbá wa yóò di ọba" Elizabeth sọ fún àbúrò rẹ̀, Margaret Rose tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́fà nígbà náà.

Onitọun náà sì fún un lésì pé o túmọ sí pé ìwọ náà ó di ọba tó bá ya, Elizabeth sì fún àbúrò rẹ̀ lésì pé bẹ́ẹ̀ ni.

Láti ara bàba-bàbá rẹ̀, Ọba George V ni Elizabeth ti ń kọ́kọ́ mọ ohun ti ó wà ní iwájú òun.

Ọ̀dọ̀ bàba-bàbá rẹ̀ yìí ló ti kọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan àti ọgbọ́n inú òhun òye ikùn tó ń lò lónìí, kí bàbá náà tó gbésẹ̀ lọ́dún 1936.

Bàba-bàbá rẹ̀ ló fún un ní orúkọ ìnagijẹ 'Lilibet', nígbà tí yóò fi pé ọmọ ọdún mẹ́ta nínú oṣù kẹrin ọdún 1929, Elizabeth ni wọ́n yà sára ìwé ìròyìn "TIME magazine".

Ní ọdún 1929 ọ̀hún bákan náà, ni bàba-bàbá Elizabeth ní à fi kí wọ́n gbé ọmọọmọ òun wá rí òun ní Bognor Regis, kí ara òun tó fà, tó le balẹ̀.

Ní àkókò yìí ni George V tí ní ìrètí pé lọ́jọ́ kan, Elizabeth yóò jẹ Ọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì nígbà tó wí fún ọmọ rẹ̀, bàbá Elizabeth pé ẹ̀gbọ́n rẹ̀, David kò ní èròńgbà láti jẹ ọba.

Gẹ́gẹ́ bí àlàyé Morshead, ó ní láti kékeré ní Elizabeth tí ń fihàn pé ọmọ ọlá ni òun nígbà tí àwọn akọ́dà bá ń bẹ́rí, tí yóò sì máa fi ọwọ́ dá wọ́n lóhùn láti fún wọn ní àṣẹ.

Ó ní ó jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu pé ọmọ ọdún mẹ́ta mọ̀ pé ọwọ́ jíjù àti orí mímì ni òun nílò láti fún àwọn akọ́dà láṣẹ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ọba.

Lẹ́yìn tó pé ọmọ ọdún mẹ́rin lọ́dún 1930, àwòrán ọmọ ọba Elizabeth wọ inú owó pọ́ùn.

Ọdun 1929 ni Elizabeth wa pẹlu Baba-baba rẹ ni Bognor Regis

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọdún méjì lẹ́yìn èyí, nígbà tó pé ọmọ ọdún mẹ́fà ní wọ́n tún fi àwòrán rẹ̀ sara owó Sẹ́ǹtì mẹ́fà.

Gbogbo ìgbà tó bá ṣeré jáde ní àwọn ènìyàn máa ń ṣí fìlà fún un nitori pé wọ́n ti damọ̀ nínú owó náà.

Nígbà tó pé ọmọ ọdún mẹ́fà, fúnra rẹ̀ ló fi ìwé ìpè síta pẹ̀lú àkọlé ìbẹ̀rẹ̀ orúkọ rẹ̀ lábẹ́ adé.

Gbogbo ìgbà yìí ló ti di gbajúgbajà, tí àwọn ènìyàn sì ti ń fojú sí i lára gẹ́gẹ́ bí ẹni tí yóò jẹ́ ọba àti pàápàá àwọn ọ̀rọ̀ tó máa ń sọ.

Ní ọmọ ọdún mẹ́jọ ló ti sọ wí pé "bí mo bá jẹ ọba, máa ṣe òfin pé ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ gún ẹṣin lọ́jọ́ Àìkú, àwọn ẹṣin náà nílò láti máa sinmi."

Pẹ̀lú gbogbo àwọn ẹ̀rí tó fojú hàn, ó jọ pé Elizabeth ti mọ̀ ọjọ́ iwájú tí òun ní láti ọmọ ọdún méje, ṣaájú kí ẹ̀gbọ́n bàbá rẹ̀ tó ní òun kò jẹ ọba mọ́.

Idile Ọba

Oríṣun àwòrán, Getty Images