Electric tarrif hike: Ìjọba àpapọ̀ jáwọ́ lórí àfinkún owó iná mọ̀nàmọ́ná fún ìgbà díẹ̀

Oríṣun àwòrán, twitter/Ministry of power nigeria
Ijọba apapọ ti jaws lori eto afikun owo ina mọnamọna ti ajọ to n ṣakoso ẹka naa kede lọjọ diẹ sẹyin.
Ijọba apapọ ke si ajọ NERC lati sinmi lori afikun owo ina naa titi di igba ti igbimọ tẹẹkoto ti wọn gbe kalẹ lati ṣe ayẹwo rẹ yoo fi pari iṣẹ wọn lopin oṣu yii.
Minisita fun ọrọ ina mọnamọna, Sale Mamman ṣalaye ninu atẹjade kan to fi sita loju opo Twitter rẹ pe, yoo dara ki wọn fi ikuluku pẹlu awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ naa ki wọn lee fi ẹnu ọrọ jona si ibi kan naa.
Ni ọjọ diẹ sẹyin ni ajọ to n ṣakoso ẹka ipese ina mọnamọna lorilẹede Naijiria, NERC kede pe afikun ti de ba owo ori ina mọnamọna lati naira meji lori oṣuwọn ina mọnamọna kan si naira mẹrin.








