Aminat Abiọdun: Ọjọ́ Satide ni Iyalode kí ayé pé ó dìgbóṣe

Eto ti n lọ lọwọ ni igbaradi fun isinku Iyalode ilẹ Ibadan, Alhaja Aminat Abiodun ẹni to jade laye lọwurọ ọjọ ẹti l'ẹni ọdun mẹtalelaadọrun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Akanṣe adura yoo waye fun oloogbe ni aago mẹrin irọlẹ oni tii ṣe ọjọ Aiku, ninu ọgba ile iṣẹ tẹlifisan ipinlẹ Ọyọ, (BCOS) to n bẹ ni agbegbe Baṣọrun nilu Ibadan.
Akanse adura naa yoo waye saaju eto isinku nile oloogbe to kalẹ si Oluwo Nla ni agbegbe Baṣọrun nilu Ibadan.

Awọn asiwaju ẹsin, aṣoju ijọba, oniṣe ọwọ, oniṣowo ati awọn ẹgbẹ awujọ ni ireti wa wipe wọn yoo peju pesẹ lati ṣe ẹyẹ ikẹhin fun Iyalode ilẹ Ibadan.










