Bode George: Òòtọ́ ni ìkìlọ̀ Obasanjọ ati Soyinka
Eekan oloṣelu Naijiria, oloye Bode George ti ni iwa ọkanjua lo n yọ Asiwaju Bola Ahmmed Tinubu lẹnu.
Nin u ifọrọwanilnuwo kan pẹlu BBC Bode George ni "adúrú ọ̀rọ̀ tóo ti kó jọ nílìí eko yìí lásán, ó yẹ kóo jẹ́ kó ran ọmọ ìyá ẹlẹ́pà, ẹni í kò rílé gbé ".
Agba ẹgbẹ oṣelu People's Democratic Party (PDP), oloye Bode George se ifọrọwerọ pẹlu awọn akọroyin nilu Eko.
Nibẹ lo ti dahun ibeere loriṣiiriṣii lori eto oṣelu Naijiria ati bi nkan ṣe ri lasiko yii ninu ẹgbẹ oṣelu PDP.
- Ìjọba Buhari kìí ṣe ọ̀nà àbáyọ síṣòro Naijiria -Jiti Ogunye
- Láti 1999 títí di 2021, wo àwọn ààrẹ tó jẹ ní Nàìjíríà
- Fayemi dá ọ̀gá ilé ẹ̀kọ́ gíga Health Tech Ijero dúrò lẹ́nu iṣẹ lẹ́yìn tí akẹ́kọ̀ọ́ 100 déèdé di èrò iléèwòsàn
- Ìdí rèé tí ọ̀gágun 30 fi gbọdọ̀ kọ̀wé fipò sílẹ̀ nítorí ìyànsípò olórí ọmogun tuntun
- Àwọn ọ̀dọ̀ wa ò kí ń ṣe òkú ní Nàìjíríà, ẹ jẹ́ kí wọ́n wà ní gbogbo ìpele ìpinu - Ooni
- Àwọn ọ̀nà kan dí mọ́ mi torípé mo jẹ ọmọ King Sunny Ade yàtọ̀ fún àǹfàní tí mo jẹ - Emperor Adegeye
Bode George ni Tinubu kò mọ pé ebi n pa àwọn ara ilu rara.
O ni loju toun Asiwaju Tinubu n ko ọrọ ipinlẹ Eko pamọ ni.
Lasiko to n dahun ibeere lori bi awọn ọmọ ẹgbẹ PDP ṣe n yalọ si ẹgbẹ oṣelu APC lasiko yii, Bode George ni ẹgbẹ mejeeji yatọ sira wọn.
O ni wọn a to rii pé ayé pé meji nitori ominira ti wọn n ri ni PDP ko le tete tẹ wọn lọwọ ni APC ti wọn lọ.
Nigba ti Bode George n dahun ibeere lori ayajọ iṣẹjọba Alagbada ti Democracy Day tọdun 2019, o ni iran Yoruba ni lati kọgbọn sii fun itẹsiwaju to yẹ.
Yoruba ni Bọmọ ko ba ba itan, o maa n ba arọba to jẹ baba itan, Bode George ni asiko ti to ki a ma kọ awọn nipa ohun to ti ṣẹlẹ sẹyin ni June 12 ati May 29.

