Bọde George: Àwọn èèyàn mọ ẹni to yìnbọn pa Adeniyi Aboriṣade
Mo mọ ẹni tó pa ọkọ mi nitori pe ó ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé òun a pa á.
Silifat Aboriṣade to jẹ aya oloogbe Adeniyi Aboriṣade to jẹ alaga ẹgbẹ oṣelu PDP fun Apapa nipinlẹ Eko sọ pé titi di àsìkò yìí, ọlọpaa kankan kò tii wa sọ́dọ̀ òun.
O ni ipade ẹgbẹ osṣelu PDP naa ni ọkọ oun lọ ni Eti ọsa ki wọn to yinbọn paa lọsan gangan.
Èrò Bode George PDP lórí ikú Aboriṣade, alaga PDP Apapa.
Bọde George naa ṣalaye fun BBC Yoruba pé àwọn to pa Adeniyi Aboriṣade lọsan gangan lọjọ naa kò bojú rárá.
O ni oloogbe padanu ẹjẹ to pọ ki wọn to gbee de ile iwosan.
Aya oloogbe bẹ gbogbo agbaye lati dide idajọ siku ọkọ oun.