Election Update 2019: Onímọ̀ kan ní Obasanjọ ni ko jẹ ki Atiku wọlé ààrẹ

Ìdíbò orílẹ̀-èdè Naijíríà tí wá, ó sì ti lọ sùgbọ́n àwọn ọmọ Nàijíríà sì ń sọ èrò ọkan wọn lóri ìdìbò náà.
Lára ǹkan ti wọn ń mú gbọ́ náà ni kíní ìdi gan ti ó mú Atiku fìdírẹ̀mi?
Ilé ìṣẹ́ BBC Yorùbá ṣe àkójọpọ̀ ǹkan Márun ti ó mú Atiku Abubakar fìdírẹmi nínú ìdìbò ọdún 2019
- Ọkan lára àwọn ọmọ Naàìjíríà tó bá BBC Yoruba sọ̀rọ̀ ọjọgbọ́n Dikirullai sàlàyé pé Bí Atiku ṣe wọ inú ìdíje ní ọ̀pọ̀ àbàwọn nínú nítori àwọn ǹkan tí ààrẹ Obasanjọ ti sọ nípa rẹ̀ tẹ́lẹ̀.
Àwọn abawọn òhun gẹ́gẹ́ bó ṣe sọ wá láti ẹnu Ààrẹ Olusegun Obasanjọ ti wọn ti jọ ṣe ìjọba fún ọdun mẹ́jọ, ó fi kún pé àwọn ǹkan tó sọ nípa Atiku ní àwọn ènìyàn gbàgba pé ó jẹ òtitọ nítori pe wọn gbàgba pé ó mọ̀ọ́ dárádára
Obasanjo fi kún pé Atiku kò ṣe gbara lé àti pé ajinilẹ́sẹ̀ ni Atiku lásiko ti àwọn jọ ṣe ijoba.
O fí kún pé Atiku ò fi ìgbà kankan janpata pé ìrọ ni obasanjo pa mọ oun àbi pé òun yóò gbe lọ sí ilé Ejọ

- Ìdí míràn ní pé ìpolongo ìdìbò Atíkú ń tọka si pé ìjọba oun yóò wà fún awọn olówó níkàn nígba ti ẹni ti ó sì ń ba dije timfi han gbangba pé ìjọba oun wà fún àwọn mẹkunu, pàápàá jùlọ lóri ọ̀rọ̀ kan to sọ pé àwọn ọ̀rẹ́ òun ní ẹ̀tọ́ láti jẹ ànfani òun ti òun bá di ààrẹ.
Ọjọ̀gbọ̀n Dikirullai sàlàyé pé àwọn ètò ti ààrẹ Buhari ti ń gbé kalẹ tẹ́lẹ̀ wà fún àwọn tálákà tó ń dibò jùlọ lórilẹ̀-èdè yìí.
- Wọn un ní ìdí míràn tún ni pé ọ́wọ́ Atiku kò mọ ti ọ̀pọ̀ ọmọ Nàijiriia si mọ, pàápàá julọ àríwísi pé láti ìgbà to tí ń sisẹ ìjọba gẹ́gẹ́ bii aṣọ́bode ló ni owo tabua, ọ̀ps ló fẹ́ mọ ọ̀nà to gbà ri owo náà sùgbọ́n ti kò le sàlàyé.
- Ẹ̀wẹ̀, wọn tún kùdiẹ̀kudiẹ̀ pọ̀ níbẹ̀ lọ́wọ́ àjọ eléto ààbò àti ibudo ìbo, ó ni àwọn eléto ààbo ń dúnkoko mọ àwọn oludibo ní ìhà ibi ti ẹgbẹ PDP ti ni àwọn ènìyàn.
- Ìdí míràn tún ni pé ìdìbò Eko, Nassarawa, jíjí àpóti gbé àti ìpaniyàn pọ̀ nínú ìdìbò ti ó kọ́ja
O fíkun pé àṣẹ tí ààrẹ Muhammadu Buhari pa pé ki wọn pa ẹni ti ó ba ji apoti ìdìbo kún oun to jẹ ìbẹ̀ru fun àwọn ara ilú ti wọn o fi jáde lọ dibo. O ni ẹru wi pe wọn le yinbọn ti yoo si ba alaiṣeẹ kún ìdí ti wọn ko fi jáde












