Kini ọ̀nà àbáyọ sí ooru tó mú lásìkò yìí ní Nàìjíríà?

Ọmọbinrin to n mu omi nitori ooru

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Onimọ kan nipa ayipada oju ọjọ, Ọmọwe Adepẹlumi Abraham sọ pe ooru to ju boṣeyẹ lọ ni awọn ọmọ Naijiria n koju lasiko yii.

O sọ fun akọroyin BBC, Ogechi Obidiebube, pe odiwọn ooru to yẹ ko mu ni iha ibi ti orilẹede Naijiria wa ni agbaye ko yẹ ko kọja a '30 degrees', odiwọn to ba ju eyi lọ kii ṣe nkan to dara.''

Lati ibẹrẹ ọdun 2019 ni ooru to n mu ni awọn apa ibikan ni Naijiria ti n to odiwọn ìdá '35-38 degree Celsius.'

Dokita Abraham ṣalaye pe nkan pataki to n fa bi ooru naa ṣe pọ to bẹẹ ko ṣẹyin bi eroja to yẹ ko maa daabo bo awọn eniyan lọwọ oorun ti dinku pupọ, eyi lo si fa a ti oorun fi n mu to bẹẹ.

Kini ọna abayọ?

Dokita Abraham sọ pe lootọ ni ayipada oju ọjọ jẹ nkan to n banilẹru, ṣugbọn ọna abayọ wa ti awọn araalu ba le gbe igbesẹ lati mojuto o.

1. Ẹ ma dana sun idọti lọna aitọ

Burning of doti

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Onimọ naa kilọ pe ki ọmọ Naijiria dẹkun lati maa sun idọti bo ṣe wu wọn nitori eefin rẹ jẹ ọ̀kan lara awọn nkan to n fa ayipada oju ọjọ.

2. Ki amojuto wa fun awọn ileeṣẹ nla-nla

Eefin to n jade lati ileesẹ kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Eefin ati afẹfẹ gaasi to n jade lati awọn ileeṣẹ jẹ ọ̀kan lara awọn nkan gboogi to n fa oju ọjọ ti ko dara ni Naijiria.

Abraham ni eyi ko ṣẹyin bi ijọba ko ṣe mojuto ọna ti awọn ileeṣẹ n gba ti eefin sita.

3. Ma ṣe wa ọkọ̀ ti ko dara mọ loju pópó

Ọkọ ayọkẹlẹ to n ṣeefin

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọkan lara awọn nkan to tun n fa oju ọjọ ti ko dara ni eefin ara ọkọ̀.

Dokita Abraham rọ awọn awakọ ni Naijiria lati maa rii daju pe ẹnjinni ọkọ ọ̀pá to n gbe eefin jade lara ọkọ̀ wọn n ṣiṣẹ daada.

Bakan naa lo gba awọn eeyan niyanju lati maa mu omi to mọ daadaa nigba gbogbo ki wọn le fi rọpo eyi to n jade lati ilaagun lasiko yii.

O woye pe nigba ti yoo ba fi to oṣu kan si asiko yii, ooru yoo dinku, ti òjò yoo si bẹrẹ si i rọ̀.