Nàìjíríà ló wà nípò kẹfà nínú ewu ikú àìtọ́jọ́ l'ágbàáyé nítorí nkan mímú tó ní ṣúgà

Fizzy cola drink

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Iwadi tuntun kan ti fihan pe awọn nkan minu ẹlẹrindodo to ni ṣuga ninu n mu ki iku aitọjọ o pọ si

Iwadii tuntun kan ti fihan pe awọn nkan minu ẹlẹrindodo to ni ṣuga ninu n mu ki iku aitọjọ o pọ si nipasẹ awọn aisan bi i aarun ọkàn ati awọn aisan jẹjẹrẹ kan.

Atupalẹ abọ iwadii naa ti ileewosan ikọṣẹ imọ iṣegun oyinbo ni fasiti Harvard fi sita l'oṣu to kọja fihan pe bi nkan mimu ẹlẹrindodo ti eniyan n mu ba ṣe pọ to ni yoo sọ bi iku aitọjọ ṣe sunmọ ẹni naa to.

Abajade naa waye lati ara iwadii ti wọn ṣe laarin ẹgbẹrun mẹtadinlogoji ọkunrin ati awọn obinrin to le ni ọgọrin ẹgbẹrun.

Bi awọn eniyan ṣe n mu ẹlẹrindodo si ni agbaye

Iwadii naa tu aṣiri pe ibaṣepọ to lagbara lo wa laarin minu ẹlẹrindodo to ni ṣuga ninu ati iku ojiji, lati ipasẹ aarun ọkàn, ati aisan jẹjẹrẹ.

Ohun to bani ninu jẹ ju ni pe bi awọn eniyan ṣe n mu nkan ẹlẹrindodo jake-jado agbaye ti pọ si ju ti tẹlẹ lọ.

Akọsilẹ ti ileeṣẹ oluwadii Euromonitor International ṣe fihan pe nkan ẹlẹrindodo ti eniyan n mu ni agbaye lọdọọdun jẹ lita 91.9 l'ọdun 2018, tako lita 84.1 to wa ni ọdun maarun sẹyin.

Odiwọn ẹlẹrindodo tawọn eniyan n mu ni agbaye. Ni biliọnu lita (2018). Iye ẹlẹrindodo ti wọn n mu kaakiri agbaye (ni miliọnu lita) .

Ṣugbọn, awọn orilẹede wo lo wa ninu ewu ju awọn to ku lọ?

Gẹgẹ bi àtẹ to wa l'oke ṣe fihan, ẹnikan n mu ju lita ẹlẹrindodo kan lọ l'ojumọ ni orilẹede China.

Ẹlẹrindodo to wa lori àtẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ajọ eto ilera ni agbaye, WHO, si sọ pe iye ṣuga ti eniyan yoo jẹ ni ojumọ ko gbọdọ ju aadọta giramu lọ.

Iye 'Calorie' to wa ninu nkan mimu ẹlẹrindodo

Ni ọdun 2015, abajade iwadii kan ninu iwe imọ iṣegun oyinbo 'the Lancet', fihan pe awọn ọmọ orilẹede America n gba 'calorie' ti ko din ni mẹtadindinlọgọjọ sara ni ojoojumọ lati ara awọn nkan mimu to ni ṣuga ninu.

Igo tabi agolo Coca-Cola to ni odiwọn 330ml, gẹgẹ bi ohun ti ileeṣẹ naa kọ si ori ayelujara rẹ, ni giraamu ṣuga marundinlogoji, eyi to tumọ si ṣibi kekere meje.

Ajọ eto ilera ni agbaye, WHO, si sọ pe iye ṣuga ti eniyan yoo jẹ ni ojumọ ko gbọdọ ju aadọta giramu lọ.

A spoonful of sugar
Getty
Iye adùn suga

  • Giraamu 35Odiwọn suga to wa ninu agolo 330ml Coca-cola kan

  • MejeIye to jẹ ni odiwọn ṣibi ṣuga

  • 12.5 ṣibiOdiwọn ti ajọ WHO fọwọ si fun agbalagba

Orisun: Coca-Cola/WHO

Orilẹede bi ọgbọ̀n lo ti fi owo ori le awọn nkan mimu to ni ṣuga ninu. Eyi lo si yẹ ki ọpọlọpọ orilẹede wo awokọṣe rẹ.

Awọn ọmọde to n wẹ ninu odo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Bi awọn ọmọde ṣe n sanra ju boṣeyẹ lọ ti lọ soke si kaakiri agbaye

Ọkan lara nkan to n mu ki ẹru ba awọn alaṣẹ eto ilera ni ipa ti awọn nkan mimu to ni ṣuga ninu n ni lara awọn ọmọde ati ọ̀dọ́.