Energy Drink: Ìjọba fi òfin de èyí tó ń mú ǹkan ọmọkùnrin le

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ijọba ìbílẹ̀ Zambia ti fòfin de àwọn ohun mímu tó n fun àwọn ọkunrin ní àgbára (Energy Drink) láti ba àwọn obinrin lòpọ̀ lẹ́yìn ti wọn se awari pe ó ni èròja kan ninu Viagra èyi ti won ń pe ni melcine gẹ́gẹ́ bi ǹkan to ń mu ǹkan ọmọkunrin duro ṣàsàn
Ní ọdun to kọja, ọkunrin kan ni Uganda sọ pe ǹkan ọmọkunrin òun kò wálè lẹ́yìn to mu SX ti wọn ń ṣe la'ti Zambia
Awọn elétò ìlera ti wádìí ọ̀rọ̀ náà ti wọn si ri pe ẹlẹrindodo náà ni ǹkan ti wọn ń pè ni Sildenafil Citrata to jẹ èròjà gbòógi nínú Viagra, ti ìjọba Zambia pàápàá tún sọ pé àwọn yòó ṣe ìwádìí tí àwọn
Àbájáde ìwádìí Zimbabwe àti South Africa tí ìjọba Zambia gbé jáde fí hàn pe òòtọ́, àjọ tó ń ri si Ounjẹ àti Oogun ri pé Sildenafil Citrata wà nínú ẹ.
Bótilẹ̀ jẹ́ pe ilé ilé iṣẹ́ to ń se ohun mímu náà Revin Zambia kò ti fèsì lóri ọ̀rọ̀ náà.
Nínú oṣù kíní alákoso àgbà ilé iṣẹ́ náà Vikas Kapoor sọ fun BBC pé níwọn ǹkan ti òun mọ, kò si Melecine nínú rẹ̀









