U.S. Embassy: À kò ni dási ọ̀rọ̀ ìdìbò Nàìjíríà

Asia Amerik

Oríṣun àwòrán, US Embassy

Àkọlé àwòrán, A ń wo Nàìjíríà gẹ́gẹ́ bíi àdarí gbogbo ilẹ̀ Afirika tó kù, nítori náà ó ṣe pàtàkí láti jk àwokóṣe rere.

Ilẹ̀ Amẹ́rika tún ti ki Nàìjíríà kú orí ire lẹ́ẹ̀kan síi lóri ìtiraka wọn nínú títọ ìlànà ìjọba awa ara wa titi gbogbo ètò ìdìbò fi parí.

Orílẹ̀ -èdè Amẹrika fidi ọ̀rọ̀ yìí múlẹ̀ nínú àtẹ̀jáde kan tí olú ilé iṣẹ́ Amẹríkà ní Nàìjíríà fi síta lọ́nìí, pé gẹ́gẹ́ bi ọ̀rẹ́ Nàìjíríà àwọn ṣetàn láti gbáruku ti ǹkan ti àwọn ènìyàn ń fẹ ti wọn si fọ òhun ìsskan nínú ìdìbò wọn.

Àkọlé fídíò, Sẹ́gílọlá: Arúgbó awẹ́lẹ́wà tó ń ṣiṣẹ́ omidan

Wọn fi kún pé àwọn yóò ma woye lóri bi ètò ìdìbò ṣe ń lọ nítori kò sí ẹgbẹ́ tàbí ẹni kankan ti àwọn ń gbè sí lẹ́yìn.

Gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹgbẹ́ ònwoye àládani ṣe sàlàyé nínú àbájadé ohun ti wọn ri nínú ìdìbò tó kọja, ó jẹ òhun ìjákulẹ̀ pé ìròyìn kan pé àwọn ènìyàn kọ láti jade díbò, ìdúnkòko mọ́ àwọn olùdibò, ìbò rírà, kíkó àwọn ológun síta lọ́jọ́ ìdìbò àti rògbodiyàn láwọn agbègbè kan.

Ohun tó ba ni lọ́kan jẹ́ gbáà ni à si ba àwọn ẹbi tó pàdánù ẹmi àwọn ẹbi wọn nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà tó fi mọ àwọn àwọn òṣìṣẹ́ àjọ elétò ìdìbò àtí àwọn òṣìṣẹ́ elétò ààbò.

"Bí gbogbo ètò ìdìbò 2019 ṣe ń kógbá wole a rọ gbogbo àwọn tí ọ̀rọ̀ kan láti ri d;aju pé wọn ṣiṣẹ tọ ìdìbo ti kò ni kọ́nukọ́họ ninu ti o si ni àláfíà pàápàá jùlọ gbogbo àwọn ti yóò jade lọ́ dibo"

" A tún rọ gbogbo àwọn ti ọ̀rọ̀ kan tó fi mọ àjọ INEC, àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú àti àwọn eleto ààbò lati tẹ̀siwaju nínú mímu eto ìdìbò gúnregé lọ́jọ́ iwájú