CHAN 2018: Naijiria ni lati san bante won ko le - Mutiu Adepoju

Aworan Mutiu Adepoju

Oríṣun àwòrán, Ben Radford/Getty

Àkọlé àwòrán, Mutiu Adepoju jẹ gbajugbaja agbabọọlu fun Naijiria to ti kopa ni idije agbaye USA 94

Agbábọ̀ọ̀lù nígbàkan rí fun Super Eagles,Mutiu Adepoju ti kilo fun àwọn agbábọ̀ọ̀lù to'n kopa lọwọ nibi idije CHAN pe wọn gbọdọ sẹ giri niwaju awọn nigbati won ba koju Sudanni nibi ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ tó kángun si àsekágbá.

O ni idije ọun yoo pakaso o si di dandan ki wọn mura daada ti wọn ba fe ki orilẹẹde Naijiria gba ife ẹyẹ Chan fun igba akọkọ.

Naijiria gbo ewúro sí Angola lójú pẹ̀lú àmì ayò méjì sòókan nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ tó wà sáàju èyí tó kángun si àsekágbá níbi ìdíje CHAN fọ́dún 2018 tó ń wáyé ní Morocco.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àǹfàáni ni ikọ̀ náà sọnù nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ ọ̀hún kí Gabriel Okechukwu to gbá bọ́ọ̀lu wọnú àwọ̀n lopin asiko ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa.

Aworan awọn agbábọ̀ọ̀lù Ile Naijiria.

Oríṣun àwòrán, NFF/Twitter

Àkọlé àwòrán, Awọn agbábọ̀ọ̀lù Super Eagles Ile Naijiria leyin ifesewonse ti wọn ti pegede

Adepoju so fun oniroyin BBC Fiona Equere pe ai le gba bọọlu wọnu awọn alatako ni ipenija to doju ko awon iko agbaọọlu Super Eagles oun.

O ni "bi ẹ ba la'nfaani ati gba ayo wole alatako yin lemarun,ẹ gbọdọ gba wọle okere tan lemeta. Bi bee kọ,ti awọn alatako yin ba lanfaani ti wọn si gba ayo wole,o tan ni yen''

Agbabọọlu fun orilẹẹde yi nigbakan ri so wipe Naijiria le jawe olu bori nibi idije naa sugbọn wọn gbudo mura daada.

Lojooru ojokokanlelọgbon osu yi ni Naijiria yoo figbagbaga pelu Sudan nibi ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ to kángun si àsekágbá níbi ìdíje CHAN fọ́dún 2018