RCCG: Adeboye ní ó sàn láti sọ̀rọ̀ ìgbéyàwó f'àlúfà ju òbí lọ

Foluke Adebpye

Oríṣun àwòrán, Facebook/Foluke Adeboye

Àkọlé àwòrán, Foluke Adeboye gba àwọn ọ̀dọ́ ní ìmọ̀ràn
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

O ṣe pataki fun awọn ọdọ to ba ṣetan lati ṣe igbeyawo lati kansi alufa ijọ wọn saaju obi wọn.

Alufa Foluke Adeboye to jẹ aya alakoso ijọ Redeem lo gba awọn ọdọ l'Ọjọbọ pe, oniwaasu ijọ wọn lọ yẹ ki wọn kọkọ ri fun imọran nigbati wọn ba n mura lati gbeyawo ki wọn to sọ fun obi wọn.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Alufa Adeboye ti ọpọ eeyan tun mọ si Mummy G.O. tun gba awọn nimọran loju opo Twitter rẹ pe ki wọn ma ṣe fẹ iyawo lawin.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Ki oníkálùkù lọ gba káàdì ìdìbò rẹ ni gẹ́gẹ́ bii agbára láti yan ẹni tó wùú sípò.

Olori gbogboogbo fun Ijọ Redeem Christian Church of God (RCCG) ni agbaye, Enoch Adeboye ti sọ wi pe ko si ohun to kan òun ninu didasi isejọba abẹlẹ ẹgbẹ oselu APC.

Olùsọ́àgùntàn Adejare Adeboye

Oríṣun àwòrán, @PastorFOdesola

Àkọlé àwòrán, Ìròyìn kan wí pé Olórí Ìjọ Redeem, Enoch Adeboye bá Alaga ẹgbẹ́ òsèlú APC, Ahmed Tinubu sọ̀rọ̀ lóri sáà kejí fún Gomina Ipinlẹ Eko, Akinwunmi Ambode.

Baba Adeboye fi eyi lede lori ẹrọ ikansiraẹni Facebook rẹ̀, lẹyin ti Iwe Iroyin kan sọ wi pe Alaga ẹgbẹ oselu APC, Bola Tinubu sọ fun Baba Adeboye wi pe ko si ohun ti oun le sẹ si saa ẹlẹẹkeji Gomina Akinwunmi Ambode ti ilu Eko.

Ninu atẹjade naa, Baba Adeboye bu ẹnu atẹ lu iroyin wi pe, ko si itakurọsọ kankan to waye laarin Tinubu ati oun.

Adari Ijo RCCG naa wa rọ gbogbo ọmọ orilẹ-ede Naijiria lati gba kaadi idibo wọn ki wọn le se ojuse wọn ninu idibo gbogboogbo ti yoo waye ni Osu Keji, ọdun to n bọ.

Ti a ko ba gbagbe, iroyin kan wi pe Olori Ijo Redeem, Enoch Adeboye ba alaga ẹgbẹ oselu APC, Ahmed Tinubu sọrọ lori saa keji fun Gomina Ipinlẹ Eko, Akinwunmi Ambode.

Bakan naa ni ọpọlọpọ awuyewuye wa lori eni ti yoo gbe asia ẹgbẹ oselu APC fun idibo si ipo gomina ni ipinlẹ Eko.

Àkọlé fídíò, Tẹniọla: Pè mí láago tí o bá mọ iyán gún pẹ̀lú ọbẹ̀ ilá tó dùn
Àkọlé fídíò, 'A máa ń bẹ́ orí ẹni tó bá gbé imọlẹ̀ ọdún ìjẹṣu tó bá ṣubú ni'