Stade de France: Wo pápá ìṣiré tí yóò gbàlejò àsekágbá ìdíje Champions League lẹ́yìn ìkọlù tí Russia ṣe sí Ukraine

Papa iṣere Stade de France ni Paris ni yoo gbalejo aṣekagba idije UEFA Champions League ọdun 2022.

Eyi ko si ṣẹyin bi Uefa ṣe yọwọ Russia lawọ gẹgẹ bi olugbalejo idije naa nitori ikọlu ti wọn ṣe si Ukraine.

Lọjọ Kejidinlọgbọn oṣu Karun ọdun yi lo yẹ ki aṣekagba idije yi waye ṣugbọn lẹyin ipade pajawiri ti Uefa ṣe lọjọ Ẹti, wọn ni Russia ko ni gbalejo idije naa.

Uefa sọ fun aarẹ ilẹ Faranse Emmnanuel Macron pe o ṣeun fun atilẹyin rẹ ati ifarajin lati ri pe wọn gba idije yi lorileede rẹ lasiko laasigbo to n waye yi.

Pẹlu iranwọ ijọba ilẹ Faranse,Uefa lawọn yoo ri pe a gbaruku ti awọn alakoso ere bọọlu lati ri pe wọn gbe awọn agbabọọlu ati mọlẹbi wọn to ba n koju wahala nitori ikọlu yi.

Njẹ Uefa yi aaye igbalejo idije Champions League pada ri?

Igba akọkọ kọ niyi ti ajọ ere bọọlu yoo yi aaye igbalejo aṣekagba idije Champiosn League pada.

Lọdun 2020 wọn yi aaye igbalejo aṣekagba kuro lati Istanbul ni Turkey lọ si Lisbon ni Portugal nitori ajakalẹ arun Coronavirus.

Turkey y ko gbalejo idije naa lọdun to kọja ṣugbọn wn gbe kuro nibẹ lọ si Portugla nitori Covid-19.

Igba ẹlẹkẹẹta ree ti Uefa yoo paarọ aaye igbalejo idije yi ṣugbọn eleyi niiṣe pẹlu wahala ikọlu to nwaye ni Ukraine to tati ọwọ Russia wa.

Kini Russia sọ si ikede yi?

Awọn onwoye ere idaraya ati oloṣelu ni Russia ti bẹnu atẹ lu igbesẹ Uefa lati gba anfaani igbalejo idije yi ni St Petersburg kuro lọwọ wọ

Aarẹ ajọ ere bọọlu Russia Alexander Dyukov to wa ninu igbimọ alaṣẹ Uefa sọ pe ''oun ko ni le faramọ igbesẹ yi''

O sọ pe ''A nigbagbọ pe nitori ọrọ oṣelu ni wọn fi gbe igbesẹ yi.

Ajọ ere bọọlu Russia RFU maa n ri pe a ko da ere idaraya pọmọ oṣelu''

Agbẹnusọ ileeṣẹ aarẹ Dmitry Peskov fi kun pe ''idojuti nla ni pe wọn gbe iru igbesẹ yi. Wọn ko ba rii pe St Peters Petersburg lo yẹ laaye igbalejo naa''

Akọwe aṣa ni ilẹ Gẹẹsi, Nadine Dorries ninu esi rẹ sọ pe inu oun dun ''pẹlu igbesẹ to mọ́ranyin ti Uefa gbe''

" A ko gbọdọ jẹ ki Russia fọwọ ọla lo idije ere bọọlu yi lati ṣe afọmọ ikọlu alainidi ti wọn ṣe si orileede to da wa labẹ ofin''

Nibo ni awọn ẹgbẹ agbabọọlu Russia yoo ti gba ifẹsẹwọnsẹ wọn to ku?

Nibi ipade ọjọ Ẹti Uefa paṣẹ ki ikọ agbabọọlu Russia ati awọn ẹgbẹ agbabọọlu to n kopa ninu idije Champions League lati gba ifẹsẹwọnse wọn laaye miran.

Spartak Moscow ni ikọ to wa lati Russia to ṣi wa ninu idije Europa League.Wọn yoo koju RB Leipzig labala komẹsẹoyo.

Gbogbo awọn ẹgbẹ agbabọọlu ni Russia ati Ukraine yoo maa gba ifẹsẹwọnsẹ wọn laaye ibomiran titi di igba ti aṣẹ yi yoo fi yi pada.

Aarẹ ajọ ere bọọlu Russia sọ pe awọn ko faramọ igbesẹ yi tori pe ao tako ilana ere bọọlu to si tun tẹ ẹtọ awọn agbabọọlu mọlẹ.