Russia-Ukraine War: Wo àwọn àwòrán tó ń sọ nípa ogun tó ń lọ lọ́wa láàrin orílẹ̀èdè méjéèjì

Nibayi ti orilẹede Russia ti gbe ikọlu ka orilẹede Ukraine mọle, ọpọ ẹmi ti sun, dokia ti bajẹ, tawọn eeyan si n sa asala fun ẹmi wọn.

Koda, awọn asaaju orilẹede lagbaye ni wọn ti n ke si ara wọn lati dide loju oorun wọn lori ikọlu Russia si Ukraine.

Akoko yii si lo buru diẹ ni ilẹ Yuroopu bayii lẹyin ogun abẹle keji, gẹgẹ bi ọga agba fọrọ ilẹ okeere labẹ ajọ isọkan ilẹ Yuroopu, Josep Borrell se sọ.

Gẹgẹ bo se wi, ajọ EU yoo fofin to lagbara de orilẹede Russia, iru eyi ti ko tii sẹlẹ ri.

Nibayii, ẹ wa wo awọn aworan to sọ nipa bi ogun naa se n lọ ati awn ohun to ti fori sọta isẹlẹ naa.

Obitibiti ero lo peju si papa isere reluwe nilu Kylv nibayi ti ariwo ikọlu lori afẹfẹ gbode kaakiri ilu naa.

Ọpọ eeyan lo gbe baagi ati apoti ẹru lọwọ, ta si mọ boya wọn n sa kuro ni orilẹede naa ni.