You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Russia Invades Ukraine: Èèyàn méje kú, ọ̀pọ̀ farapa bí Russia ṣe bẹ̀rẹ̀ ìkọlù sí Ukraine
Kò dín ní àwọn ará ìlú méje tó ti pàdánù ẹ̀mí wọn níbi ìkọlù tí Russia ń gbé kọlu Ukraine.Olùbádámọ̀ràn Ààrẹ ilẹ̀ Ukraine kan tilẹ̀ ní ogójì àwọn ọmọ ogun ló ti kú tí ọ̀pọ̀ sì farapa.Ní báyìí, Ààrẹ Ukraine, Volodymyr Zelensky, tí kéde pé kí àwọn ọmọ ogun gba gbogbo orílẹ̀ èdè Ukraine kan, àti pé kò sí àjọṣe kankan pẹ̀lú Russia mọ́.Nínú fọ́nrán kan tó fi síta, Zelensky ní àwọn ò sojo, àwọn dúró ṣinṣin, àwọn máa borí gbogbo ìkọlù nítorí tí àwọn jẹ́ Ukraine, àwọn tí ṣetán láti koju ohunkóhun.Ṣáájú kí Russia tó bẹ̀rẹ̀ ìkọlù náà, Zelensky gbìyànjú láti yẹ ìjà náà nígbà tó ṣèkìlọ̀ pé ogun ńlá ni Russia fẹ́ dá sílẹ̀ ní Yúróòpù to si ni kí àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Russia tètè da lẹ́kun.
Káàkiri olú ìlú Ukraine ni wọ́n ti ń fọn fèrè ìkìlọ̀ níbi tí ènìyàn tí kò dín ní mílíọ̀nù mẹ́ta ń gbé.Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn ló ti ń fi ìlú sílẹ̀, tí àwọn mìíràn sì ń wá láti forí pamọ́ sábẹ́ àjà ilẹ̀ ni Kyiv.Bákan náà ni àwọn orílẹ̀ èdè tó múlè tí Ukraine ti bẹ̀rẹ̀ ìgbáradì láti gba àwọn aṣàtìpó lọ́pọ̀ yanturu.Obìnrin kan, Svetlana sọ fún BBC pé ohun tí àwọn yóò ṣe kó yẹ òun mọ́, àti pé àwọn ń gbèrò láti lọ sí ìlú mìíràn tí ààbò yóò wà fún àwọn.Ó ní ìrètí àwọn ni láti kúrò láyọ̀ nítorí àwọn ẹbí àwọn tó wà ní Mariupol ti wà nínú ìbẹ̀rù bojo.Ọkùnrin kan náà pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nígbà tí ọmọ ogún Russia ṣe ìkọlù sí Chuhuiv.
Russia ṣe ìfilọ́lẹ̀ ìkọlù sí Ukraine
Aarẹ ilẹ Russia, Vladimir Putin ti sefilọlẹ ikọlu ologun si agbegbe Donbas to wa ni ẹkun ila oorun Ukraine.
Ninu ọrọ to bawọn eeyan ilẹ Russia sọ, lo ti rọ awọn ọmọ ogun ilẹ Ukraine to n doju ija kọ igun ọlọtẹ ti orilẹede Russia n se atilẹyin fun lati gbe ohun ija wọn silẹ.
Bakan naa lo tun rọ wọn lati pada si ile wọn.
- UK fófin de bánkì márùn ún pẹ̀lu olówó Russia mẹ́ta torí làásìgbò Ukraine
- A ṣì lè yanjú ọ̀rọ̀ Ukraine ní ìtùbí-ìnùbí - Russia
- Orílẹ̀-èdè méjìlá pàṣẹ̀ pé kí àwọn eèyàn wọn kúrò ní Ukraine nítorí ogun Russia tó súnmọ́ tòsí
- Gbenga Adeyinka: Àwọn Adẹ́rinpòṣónú Nàìjíríà lè di ààrẹ
- Ohun tí ó ṣokùnfà ikú Fadlullah Agboluaje, akẹ́kọ̀ọ́ tó kú sí Ukraine ní ọjọ́ kejì tó dé ibẹ̀
- Kí ló pa akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ Nàíjíríà tó kú lọ́jọ́ kejì tó dé ilé ẹ̀kọ́ ní Ukraine?
Putin ni orilẹede Russia ko ni lero lati kọlu ilẹ Ukraine amọ o wa sekilọ pe orilẹede oun yoo doju ija kọ ẹnikẹni to ba pe awọn nija.
Amọ ijọba ilẹ Ukraine ti kede pe Putin ti ya bo orilẹede naa lọna nla.
Ninu ọrọ to kọ si oju opo Twitter rẹ, Minisita fun ọrọ ilẹ okkere nilẹ Ukraine, Dmytro Kuleba ni "Awọn ilu to dakẹ rọrọ nilẹ Ukraine ni wọn ti kọlu bayii.
Ogun ikọjuiyasini lọna aitọ ree amọ Ukraine yoo daabo bo ara rẹ, ti yoo si bori.
Gbogbo agbaye le se lati da Putin lọwọ kọ ogun to n ja, asiko si ti to lati se bẹẹ́."