Sadio Mane: Wọ́n ti fi orúkọ̀ agbábọ́ọ̀lù Liverpool sọ pápá ìṣeré kan ní Senegal

Olootu ijọba ni ẹkun Sedhiou, lorilẹ-ede Senegal, ti ṣetan lati fi orukọ ongbatarigi agbabọọlu ẹgbẹ Liverpool, Sadio Mane, sọ papa isẹre to wa ni ẹkun naa.

Agbabọọlu naa lo gba goolu pẹnraiti sinu awọn lasiko ti Senegal koju Egypt ni aṣekagba idije AFCON 2022 to sẹṣẹ pari, eyi to mu ki wọn o jawe olubori.

Ami ayo mẹrin si meji ni Terenga Lions ti Senegal fun Egypt.

Igba akọkọ si re e ti orilẹ-ede naa gba ife idije AFCON.

Olooru ijọba ni Sedhiou, Adboulaye Diop, sọ pe oun pinnu lati fi orukọ Mane sọ papa iṣere Sate de Sédhiou, lati fi ẹmi imoore awọn ọmọ bibi agbegbe naa han si "ọkunrin to n fi igbe aye rẹ sin ọmọniyan".

"Sadio Mane tọ si pe ka bu ọla fun un".

Asiko diẹ sẹyin ni Mane di aayo lọkan ọpọ miliọnu eeyan ni ilu abinbibi, nigba to jẹjẹ owo lati fi kọ ileewosan ati ile ẹkọ fun wọn.

O tun da owo si kikọ awọn mọṣalaaṣi, to si tun fun ijọba lowo lati gbogun ti ajakalẹ aarun Covid-19.

Yatọ si eyi, Mane tun pin aṣọ ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool fun awọn ara ilu abinibi rẹ, Bambali, ki wọn o ri nkan wọ lasiko aṣekagba idije Champions League ni oṣu Karun-un, ọdun 2018.

Lẹyin ti ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Senegal bori ni Afcon lorilẹ-ede Cameroon, Mane sọ pe bi oun ṣe gba akọkọ ife ẹyẹ idije naa fun Senegal, jẹ aṣeyọri to tobi ju ninu irinajo oun gẹgẹ bi agbabọọlu.