You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
AFCON 2021: Àwọn òhun tó yẹ kí o mọ nípa Afcon 2021 tí à ń gbá lówọ́ ní 2022 nítrorí Covid 19
Ninu ọrọ to gbagboro kan bayi tawọn eeyan n ran lẹnu ni ti AFCON2021.
Lati ọjọ kẹsan an, oṣu kini, ọdun 2022 ni o ti gbera sọ.
Igba kẹtalelgbọn ree ti idije naa yoo waye ti Cameroon yoo si maa gba alejo awọn agbabọọlu
Oṣu Kẹfa, ọdun 2021 lo yẹ ko waye ṣugbọn wọn wgile nitori ajakalẹ Coronavirus.
Bi ẹ ba ti n kẹfin nipa idije yi, ma ṣe iyọnu rara nitori oju opo wa ti wa ni ṣẹpẹ lati mu bi nkan ṣe n lọ wa fun yin.
Amọ ki a kọkọ la ara wa loye lori awọn nkankan naa.
Ki gan an ni AFCON?
AFCON tumọ si idije ere bọọlu fawọn orileede Afrika.
Ajọ ere bọọlu Afrika CAF lo n ṣagbateru idije yi.
Lara eredi rẹ ni pe yoo mu isọkan ba awọn eeyan ilẹ Afrika nipase ere idaraya bọọlu gbigba.
Laarin oṣu Kẹfa si oṣu Keje ọdun meji si ara wọn ni idije yi a maa waye.
Oṣu kan gbako ni wọn ma fi n kopa ninu idije yi
Nigba wo ni AFCON bẹrẹ?
Ọdun 1956 ni wọn gbero lati se ifilọlẹ idije yi lẹyin tawọn orileede mẹrin-Egypt, Sudan, Ethiopia ati South Africa da CAF sile ni Lisbon lorileede Portugal.
Amọ ni ọdun 1957 ni AFCON to bẹrẹ ni olu ilu ilẹ Sudan tii ṣe Khartoum.
Egypt, Ethiopia ati Sudan lo kopa ninu idije akọkọ
Wọn yọwọ South Africa lawo nitori pe wọn ni awọn agbabọọlu alawọfunfun lawọn fe fi kopa ninu idije naa.
Orileede meloo lo n kopa ninu idije AFCON?
Nigba ti AFCON kọkọ bẹrẹ orileede mẹrin nikan lo kopa ṣugbọn nigba ti yoo fi di ọdun1961, awọn orileede mẹsan an mii darapọ mọ wọ.
Awọn orileede bi Naijiria ati Tunisia bẹrẹ si ni kopa lọdun 1963.
Ni 1998 awọn to n kopa ninu AFCON di mẹẹdogun. Iye yi lekun si ni 2017 nigba ti wọn faaye gba orileede mrinlelogun lati kopa.
Anfaani wo ni idije AFCON mu wa fawọn to n kopa
Orileede to ba gba ife ẹyẹ, awọn agbabọọlu wọn ọgbọn yoo gba ami ẹyẹ ti wọn fi wura rọ lati orileede Italy.
Awọn to ba se ipo keji naa yoo gba ami ẹyẹ fadaka ọgbọn .
Bẹẹ naa ni wọn yoo fun awọn to ba se ipo kẹta ni ami ẹyẹ ti wọn naa.
Iwe ẹri mo kopa ni wọn maa n fun awọn to ba ṣe ipo kẹrin
Ọjọ pẹ ti Naijiria ti n kopa ninu idije AFCON
Ikọ Super Eagles Naijiria bẹrẹ si ni kopa ninu idije AFCON lọdun 1963 nibi ti wọn ti gba goolu mẹwaa sara ti wọn si ja wọn ni ipele akọkọ.
Igba ikọkandinlogun ree ti idije AFCON yoo waye.
Ìrìn àwọn orílẹ̀-èdè wo ni yóò tẹ̀ fún arawọn báyìí tí ìdíje AFCON2021 bẹ̀rẹ̀
Lati igba ti wọn bẹrẹ si ni kopa, Naijiria gba ife idije naa lẹẹmẹẹta 1980, 1994 ati 2013
Awọn nkan mii to yẹ ki o mọ nipa AFCON
Orileede Egypt lo ti gba ife ẹyẹ AFCON nigba to pọ julọ.
Igba meje ọtọọtọ ni wọn ti gba a kọja.