Champions League: Chelsea jogodo nínú ìdíje FA Cup, báwo ni ọ̀rọ̀ yóò ṣe rí pẹ̀lú Man City?

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Gbangba yoo dẹkun, kedere yoo si bẹẹ wo lalẹ ọjọ Abamẹta nigba ti ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea ati Manchester City ba waako ninu ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba idije UEFA Champions League ti saa bọọlu 2020-2021.

Papa iṣere Estadio do Dragao ni Porto lorilẹede Portugal ni ifẹsẹwọnsẹ to lamilaaka ọhun yoo ti waye ni deedee ago mẹjọ alẹ.

Gbogbo eto lo ti to fun ifẹsẹwọnsẹ naa lati gberasọ lalẹ ọjọ Satide.

Awọn ohun to yẹ ki ẹ mọ niyii nipa ifẹsẹwọnsẹ Champions League alẹ ọjọ Abamẹta ni Porto.

Akọkọ ni pe, ẹgbẹ agbabọọlu ilẹ Gẹeṣi ni Chelsea ati Man City ti wọn yoo jọ ta kangbọn ninu aṣekagba idije UEFA Champions League.

Man City ko tii gba ife ẹyẹ Champions League ri, koda igba akọkọ ree ti wọn n kopa ninu aṣekagba idije naa.

Chelsea ni ti wọn ti gba idije naa lẹẹkan nigba ti wọn lu Bayern Munich lọdun 2012.

Chelsea ti fagba han Man City lẹẹmeji laipẹ yii ninu idije FA Cup ati idije Premier League.

Ẹgbẹrun mẹrindinlogun abọ oloworan ni yoo lanfaani lati wo ere bọọlu naa ni Porto.

Awọn ikọ mejeeji lawọn agbabọọlu dantọ lati kopa ninu idije alẹ ọjọ Satide ayafi Ilkay Gundogan Man City to kọlu Fernandinho nigba ti wọn n gbaradi.

Akọnimọọgba Man City, Pep Guardiola ti gba ife ẹyẹ Champions League nigba meji lasiko to fi jẹ olukọni Barcelona.

OLukọni Chelsea ni tiẹ, Thomas Tuchel ko ti gba ife naa ri gẹgẹ bi akọnimọọgba.

Amọ, oun lo gbe ẹgbẹ agbabọọlu PSG wọ aṣekagba idije ọhun ni saa bọọlu to lọ, ṣugbọn Bayern Munich fagba han wọn lati gba ife naa.