May 29: Àwọn ọmọ Naijiria yóò mọ rírì Ààrẹ Buhari lẹ́yìn tó bá kúrò lórí oyè tán - Ìjọba àpapọ̀

Ijọba Naijiria ti sọ pe awọn araalu yoo mọ ipa iṣejọba Aarẹ Muhammadu Buhari lẹyin to ba pari saa rẹ tan lọdun 2023.

Amugbalẹgbẹ Aarẹ lori iroyin ati ipolongo, Femi Adesina lo sọ ọrọ naa ninu atẹjade kan to fi lede lati ṣami si ọdun kẹfa Buhari lori alefa.

O ni "o ku ọdun meji ki ijọba yii pari, lagbara Ọlọrun, gbogbo awọn to n bu ẹnu atẹ lu ijọba yii ni yoo ṣi gbe oriyin fun un."

Gẹgẹ bi Adesina ṣe sọ, ohun ribiribi ti ijọba Buhari ti gbe ṣe ko lonka.

Amugbalẹgbẹ naa mẹnuba awọn akanṣe iṣẹ ti Aarẹ Buhari ti ṣe bii awọn ohun amayedẹrun, idagbosoke igbeaye ọmọniyan atawọn iṣẹ takun-takun mii ni oniruru ẹka.

Adesina ṣalaye pe "Lati ori awọn ohun amayederun si eto iṣuna, eto ẹkọ, eto ilera, ere idaraya, gbigbogunti iwa ajẹbanu, ọrọ epo rọbi ati bẹẹ nẹẹ lọ, awọn aṣeyọri wọnyii yẹ ko wu awọn ọmọ Naijiria lori."

"Awọn eeyan kan n sọ pe awọn ko ri nnkankan ti a n ṣe ati pe awọn ko gbọ nipa aṣeyọri kankan, lara awọn aṣeyọri wa ree."

Lẹyin naa lo bẹrẹ si n tọka si awọn nnkan ti ijọba to wa lode yii ti ṣe lẹsẹsẹ.

Lara awọn nnkan to mẹnuba ni awọn akanṣẹ iṣẹ bii ọkọ oju irin lati Eko si Ibadan, Itakpe si Warri, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

O tun mẹnuba awọn atunṣẹ papakọ ọkọ ofurufu bii ti ilu Eko, Abuja, Kano ati Port Harcourt.

Ọpọ awọn ọmọ naijiria lo ti bẹrẹ si fi erongba wọn lede lori atẹjade naa, bi awọn kan ṣe n ki Aarẹ ku iṣẹ takuntakun, lawọn mii n sọ pe nnkan ti bajẹ ju ti igba ti Aarẹ kọkọ gori alefa lọ.

Ìjọba Buhari ti já àwọn ọmọ Nàìjíríà kulẹ̀, àwọn aṣòfin yarí àmọ iléeṣẹ ààrẹ fèsì pé...

Oni ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu karun un ọdun 2021 lo pe ọdun mẹfa ti Aarẹ Muhammadu Buhari di aarẹ orilẹede Naijiria labẹ ijọba awarawa.

Ẹgbẹ oṣelu PDP lo ti ṣejọba lati ọdun 1999 ti Naijiria ti pada si ijọba awarawa titi di 2015 ti Buhari wọle ibo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC.

Ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu karun un ọdun 2015 ni wọn bura wọle fun Buhari gẹgẹ bi aarẹ lẹyin to fẹyin Goodluck Jonathan gbalẹ ninu ibo gbogbogbo ọdun naa.

Buhari tun wọle ẹẹkeji lọdun 2019 nigba ti oludije PDP mii, Atiku Abubakar tun fidi rẹmi ninu ibo aarẹ.

Aarẹ Buhari ṣeleri lati pese eto aabo to mọyan lori ati itaji ọrọ aje Naijiria lẹyin to wọle tan.

Ṣugbọn ero awọn eeyan ṣọtọọtọ lori ijọba Buhari lati bii ọdun mẹfa sẹyin.

Nigba to n sọrọ ni tiẹ, oluranlọwọ aarẹ lori ọrọ iroyin ati ilukoro, Femi Adesina ṣapejuwe Buhari gẹgẹ bi ẹni to ti ṣe aṣeyọri nla laarin ọdun mẹfa to gori aleefa.

Ninu atẹjade ti Adesina fi sita, o ṣalaye pe awọn ti wọn ko ba ni ki ọrọ oṣelu bọ nikan lo le ri aṣeyọri ti Buhari ti ṣe lati ọdun 2015 si akoko yii.

Adesina ni lai ṣe ani-ani ọpọ eeyan to fi mọ awọn alatako gan an ni yoo gboriyin fun Buhari nigba ti ijọba rẹ ba pari lọdun 2023.

O ni ijọba Buhari ti ṣiṣẹ ribiribi lẹka eto ẹkọ, eto inawo, ere idaraya, ileegbe, igbayegbadun araalu ati awọn ẹka mii.

Amọ, awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu to kere julọ nile igbimọ aṣoju-ṣofin niluu Abuja ti sọ pe ijọba Buhari ti kuna fun ọdun mẹfa.

Awọn aṣofin naa ni ni gbogbo ọna ni ijọba Buhari ko ni ṣe aṣeyọri lati ọdun mẹfa to ti wa lori oye.

''Laye ijọba Buhari ni eto abo mẹhẹ ti ko si ri ojutu sii, iwa ajẹbanu ti pọ sii ni ijọba Buhari, ọrọ aje Naijiria dẹnu kọlẹ, bakan naa ni ẹlẹyamẹya tun pọ sii.

Bi ijọba Buhari ti n ṣe nkan pẹlu igboya ta ni yoo mu mi, bi ko ṣe tẹ le ofin nigba mii, bi wọn ṣe n ṣe èrú ninu ibo, ati bi ijọba APC ṣe n fi ẹtọ awọn araalu dun wọn n kọ wa lominu gẹgẹ bi aṣofin.

Awọn eto ti APC n ṣe labẹ ijọba Buhari ti jẹ ki airi ṣiṣẹ ṣe pọ si, gbogbo nkan lo wọn gogo, owo naira ko ni itumọ kankan mọ.

Orilẹede Naijria ti di ibi ti iṣẹ ati oṣi ti n ba awọn eeyan finra julọ lagbaaye labẹ ijọba Buhari.

Ijọba Buhari ko nilo lati ṣe ayẹyẹ tabi ayajọ ọjọ to de ijọba, ohun ti Buhari nilo ni pe ko fi asiko yii ronu ati wa ojutu si iṣoro to n koju Naijiria lọwọ yii,'' olori ẹgbẹ oṣelu to kere nile, Ndudi Elumelu lo ṣalaye ọrọ yii ninu atẹjade to fi sita.