Ìgbà ọ̀tun! Lampard kó ìyà lọ, Tuchel kó ire de Chelsea

Igba kan n lọ, igba kan n bọ, aye duro titi lae.

Eyi lo difa akọnimọọgba Chelsea tẹlẹri, Frank Lampard ti o ti idi itan bayii ni ẹgbẹ agbabọọlu naa.

Olori ẹgbẹ agbabọọlu naa, Roman Abramovich jawe gbẹle ẹ fun Lampard lẹyin ti nkan ko ṣẹnu 're mọ fun Chelsea ninu awọn ifẹsẹwọnsẹ ti wọn n kopa ninu rẹ.

Ṣugbọn ni bayii, omi tuntun ti ru, ẹja tuntun si ti wọ lẹgbẹ agbabọọlu Chelsea lẹyin ti Tomas Tuchel di akọnimọọgba tuntun fun Chelsea.

Ọmi ni Chelsea gba pẹlu Wolves ninu ifẹsẹwọnsẹ akọkọ ti Chelsea ti gba lẹyin ti Tuchel de.

Amọ, ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea fakọyọ lọjọ Aiku, lẹyin ti bo Burnley mọlẹ nile wọn pẹlu ami ayo meji sodo.

Balogun ikọ Chelsea, Cesar Azpilicueta lo gbayo akọkọ sawọn fun Chelsea ki Marcos Alonso to fọba lee nigba to ku diẹ ki ifẹsẹwọnsẹ naa pari.

Ipo kẹsan ni Chelsea wa bayii lori tabili idije English Premier League.