You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Silhouette Challenge: Pásítọ̀ Adeboye korò ojú sí ìwà ṣíṣí ara sílẹ̀ lórí ayélujára
Ọpọlọpọ eniyan lo ti n fi ero wọn han lori aworan ati fidio #Silhouette Challenge. ti awọn eniyan n fi sita lẹyin ti wọn ti kuro lori #BussItChallenge.
Ninu Silhouette Challenge yii ni wọ̀n ti n fi aworan ihooho ara wọn sita ninu okunkun.
Bi awọn eniyan kan ṣe n sọ wi pe o dara, ni awọn miran sọ wi pe ko bojumu rara.
Awọn gbajumọ lawujọ ati awọn osere naa ko gbẹyin ninu awọn to kopa ninu #Silhouette Challenge lori oju opo Twitter.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo àwọn ọmọ Yorùbá tó ń ti Sunday Igboho lẹ́yìn bí i iké
- Ẹ múra mi sílẹ̀ ẹ̀yin apààyàn Fulani ní Ogun, mò ń bọ̀ kánkán - Sunday Igboho
- Àwọn olóṣèlú ti ń fowó bẹ̀ mí kí n má bá Fulani jà torí ìbò 2023, àmọ́ o ti bọ́ - Sunday Igboho
- Seyi Makinde lo ṣí ilé mi tó jóná pẹ̀lú ‘transformer 500kva’ - Sunday Igboho
- Olóṣèlú ti tọwọ́ bọ ọrọ Igboho àti ìṣòro Fulani, mo gbọdọ̀ ṣọ́ra - Gani Adams
- Ògo ilẹ̀ Yorùbá ní Sunday Igboho jẹ́, ẹ́ kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ìràwọ rẹ̀ wọlẹ̀ - OPC
- Ta bá gba Seriki Fulani padà sí Igangan, a fi ọwọ́ ara wa, pa ara wa ni - Aráàlú
- Bí Sunday Igboho bá tàpá sófin, kí lẹ ṣe fáwọn ọ̀daràn Fulani tó ń pa èèyàn - Gani Adams
- Sunday Igboho ṣọ́ra ṣe, jẹ́ kí Seyi Makinde ṣiṣẹ́ tí òfin gbé le lọ́wọ́ - Ooni Ife
Kini #Silhouette Challenge to n ja ranyin lori Twitter?
Awọn to n kopa ninu Kini #Silhouette Challenge ni wọn n fi fidio ara wọn lede loju opo Twitter nibi ti wọn ko wọ aṣọ.
Fidio naa yoo safihan awọn awẹlẹwa ti wọn n ṣe afihan ara wọn ninu okunkun lai wọ aṣọ.
Pupọ ninu wọn yoo kọkọ safihan ara wọn ti wọn ba wọ aṣọ, lẹyin naa ni wọn yoo wa bọ aṣọ ti wọn, yoo si fi ihoho ara wọn han.
Amọ ohun ti wọn n lo ninu fidio naa ni Vin Rouge filter lati Snapchat, eleyii ni yoo sọ fidio ihoho wọn di pupa ati dudu, ti yoo si dabi ojiji ara eniyan ni wọn n wo.
Awọn ohun to n dun mọ awọn eniyan to fẹran rẹ ni wi bi o ṣe n yipada lati fidio to safihan wọn ninu aṣo si eleyii to safihan ojiji wọn ni ihoho.
Ati ọmọlẹyin Kristẹni, Musulumi ati bẹẹ bẹẹ lọ ni wọn n kopa ninu #Silhouette Challenge lori Twitter.
- Ooni Ile ife ṣàlàyé ohun tí Tinubu níló fún ilépa ipò ààrẹ lọ́dún 2023
- Gbèǹdéke ku àsìkò díẹ̀, Seriki Fulani fohùn ránṣẹ́ sí Sunday Igboho
- Okuǹrin oníyàwó mẹ́ta fún ọmọ ọdún méjìlá lóyún, ó ní ₦200 ni òun fi tàn án jẹ
- Wo nkan tó mú òṣìṣẹ́ akólẹ̀-kódọ̀tí fún LAWMA kàgbákò ikú l'ẹ́nu iṣẹ́ nípìnlẹ̀ Eko
- Buhari buwọ́lu bílíọ̀nù N6.45b láti dá ibùdó afẹ́fẹ́ gáàsì sílẹ̀ fún ìtójú àwọn alárùn covid-19
Silhouette Challenge: Ẹ yé ṣí ìhòhò ara yín síta lórí 'Social Media' - Pásítọ̀ Enoch Adeboye
Lara awọn to tako Silhouette Challenge ni adari ijọ irapada, Redeemed Christian Church of God, Pásítọ̀ Enoch Adeboye.
Pasito Adeboye sọrọ tako fifi ihọho ẹni han lori ayelujara, eleyii to ni yoo le ẹmi mimọ kuro ni ara eniyan.
Loju opo Twitter ni Baba Adeboye ti ni awọn ohun ara lo fi ara han gẹgẹbi bibeli ṣe sọ ninu Iwe Galatia 5:19-21.
''O ro wi pe o le e wo ihoho eniyan lẹẹkan ko o gboju kuro, ko ṣeeṣe, wa a pada sibẹ''
''Oun pa ina ẹmi mimọ to wa ninu rẹ, ti o ko ba kiyesi ara''
''Nitori naa, mo rọ yin lati ma ṣe pa ina ẹmi mimọ to wa ninu rẹ lailai''
Ẹ wo esi ti awọn eniyan fun Pasito Adeboye lori #Silhouette Challenge
Ọpọlọpọ awọn eniyan lo bu ẹnu atẹ lu ọrọ ti Baba Adeboye sọ, amọ awọn miran gboriyin fun wi pe ọrọ iwuri.
Awọn to bu ẹnu atẹ lu u ni wi pe ọrọ ti ko ṣe koko ni Baba Adeboye ran isan mọ, to fi awọn ọrọ to ṣe koko.
Wọn ni baba ko sọrọ si awọn ohun to ṣe pataki bii awọn igbesẹ ijọba to mu aye niran fun awọn eniyan.
Awọn miran tun bere lọwọ baba boya o ti wo fidio ihoho naa lo ṣe mọ nkan to wa nibẹ.
Amọ awọn ẹlomiran gbe orinyin fun baba, ti wọn si ni ẹsẹ ni lati fi ihoho eniyan si ita gbangban.
Bakan naa ni awọn miran sọ wi pe ẹsẹ ma n ba ọjọ ọla eniyan jẹ ni, ti kii si jẹ ki eniyan ṣe rere.
Awọn miran to tun sọrọ tako #Silhouette Challenge ni akọrin ogo,Mercy Chinwo , Reno Omokri ati bẹẹ bẹẹ lọ.