You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Sunday Igboho: Lóòtọ́ọ́ ní Bola Tinubu fún mi ní ₦2m láti máṣe dá sí ìbò Mimiko l‘Ondo
Oloye Sunday Adeyemo, ti ọpọ eeyan mọ si Sunday Igboho ti salaye nipa ajọsepọ to ni pẹlu asaaju ẹgbẹ oselu APC, Oloye Bola Ahmed Tinubu.
Igboho, lasiko to n kopa lori eto kan lori ayelujara ti agba akọroyin, Dele Momodu se agbatẹru rẹ, lo ti salaye nipa ohun to da oun ati Tinubu pọ.
Igboho ni lootọ ni oun lọ sepade pọ pẹlu Tinubu nile rẹ to wa ni Bourdillion nilu Eko nitori Sẹnetọ Rashidi Adewolu Ladoja to jẹ baba fun oun lo pasẹ pe ki oun lọ.
- N kò fẹ́ oyè ọ̀gá àgbà páta fún ikọ̀ Amotekun nílẹ̀ Yorùbá - Sunday Igboho yarí
- Sunday Igboho yarí lórí àwọn ‘ọ̀rọ̀ ìbajẹ́’ tí Babafemi Ojudu kọ nípa rẹ̀
- Àwọn jàǹdùkú yìnbọn sókè lọ́pọ̀ ìgbà kí wọn tó jó ilé Sunday Igboho - Ọlọ́pàá Oyo
- N kò le ṣàtìlẹyìn fún arúfin láti tán ìṣòro ètò ààbò - Seyi Makinde
- Àwọn ọ̀tá kan ń lo ìwà akọni Sunday Igboho láti bà mí lórúkọ jẹ́ - Gani Adams
Ajijagbara fun ilẹ Yoruba naa ni lasiko ti eto idibo gomina fẹ waye nipinlẹ Ondo, ti Olusegun Mimiko ti kopa ninu rẹ, ni isẹlẹ naa waye.
O salaye pe lasiko ipade naa ni Tinubu sọ fun mi pe n ko gbọdọ se atilẹyin fun ẹgbẹ oselu PDP lasiko eto idibo naa nitori iwa aidaa ti wọn hu si Ladoja, to jẹ baba fun oun.
Igboho ni "N kò gbà owó lọwọ Tinubu rí àmọ́ o fún mi ní miliọnu meji naira lasiko abẹwo mi naa,pe kí n fi ra epo sì moto.
Iya ti PDP fi jẹ ladoja ní ko jẹ ki n sisẹ fun PDP, mo sì ṣe ohun tí Tinubu fe ki n se lasiko naa."
Agbara to daju wa lọwọ iran Yoruba:
Igboho, lasiko to n salaye iru agbara to ni sọ pe lootọ ni agbara wa nilẹ Yoruba, amọ awọn alaisootọ kan lo n mu ebu ẹyin ba a.
"Yoruba ni oogun lọwọ. Onirọ tí pọ ni kò jẹ ka naani nnkan ta ni. Ologun kii se ìkà báwọn Musulumi ati Kristiẹni tí lérò rẹ.
Ọlọ́run dá èwe àti egbò, Ọlọrun lo máa ń fún èèyàn, tí èèyàn kò bá ti sí lo."
Ladoja ni baba mi, ko dalẹ mi ri:
Nigba to n salaye iru ajọsepọ to ni pẹlu Rashidi Ladoja, Igboho ni baba oun lo jẹ, tori ọdọ rẹ ni oun de si lẹyin ti ogun Modakeke ati Ife pari, ninu eyi ti oun ti kopa.
"Lootọ ni n kii ba oloselu se amọ mo ba awọn mẹta kan se pupọ. Ladoja, bàbà dáadáa ni, mo fẹran wọn, kìí yẹ àdéhùn.
A jọ dúró tì ara wa. Mo tẹ́lẹ̀ Lam Adesina fún ọdún kan, àti Ladoja. Mo tún bá Oyinlola ṣe ni Osun."
Seyi Makinde lo si ile mi to jona:
Nigba to n dahun ibeere lori ibasepọ rẹ pẹlu gomina ipinlẹ Oyo, Enginia Seyi Makinde ati idi ti aarin wọn ko fi gun, Igboho ni eyi ko ri bẹẹ rara.
"Èmi àti Makinde, ibasepọ wá dán moran. Ladoja ni mo n tẹle. Ibi tí kò ba lọ, n kii lọ. Makinde lo ba mi sí ilé mi tó jọna.
Ó tún fún mi ní ẹrọ amunawa alagbara 500KVA lati gbe mi larugẹ ni adugbo ti mo n gbe, bẹẹ ni Ladoja lo pasẹ fun wa pe ka dibo fún Seyi
Makinde, ta si sisẹ fún wọn lọjọ idibo.
- Kìí ṣe àgbẹ̀ nìkan ni ọ̀daràn darandaran n pa, wọ́n n pa àwa Fulani nàá - Ààrẹ Miyetti Allah
- Orí mi wú báwọn oríadé ṣe ní kò sí ààyè mọ́ láfi fi ọmọ Yorùbá ṣètùtù Nàìjíríà - Sunday Igboho
- Bukola Saraki sọ̀rọ̀ sókè lórí ìgbésẹ̀ Sunday Igboho
- Afurasí Fulani daran-daran fi ìbọn fọ́ ìka obìnrin kan lójú pópó
- Sunday Igboho sọ̀rọ̀ fún ìgbà àkọ́kọ́ lẹ́yìn àbẹ̀wò rẹ̀ sí Igangan
Èmi kii se gìrì mọ oloselu miran lẹyin Ladoja. Ń ko dalẹ rẹ rí, ohun ti ko bá lọwọ sì, èmi kii se.
Ọpọ lo fi owó lọ mi àmọ́ mo kò ọ, n ko le kúrò lẹyin Ladoja bo tilẹ jẹ pe a ko se oselu mọ."
Ko si ija laarin emi ati Gani Adams:
Oloye Sunday Igboho tun mẹnuba bi aarin oun ati Aarẹ Ọna Kakanfo tilẹ Yoruba, Iba Gani Adams ti ri lasiko yii.
O ni kò sí nkankan bíi ìjà laarin oun àti Gani Adams, awọn si jọ ń ṣiṣẹ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí ni.
O fikun pe Gani Adams gan ti ke sita lori bawọn ọdaran kan laarin awọn Fulani se n huwa ika nilẹ Yoruba, eyi ti ko ba oun naa lara mu rara.
"Òun náà tí sọrọ tako ìwà àwọn darandaran yìí, a si dijọ n sisẹ pọ ni, ko si ija rara laarin wa."
N ko mọ Nnamdi Kanu ri, a ko sọrọ ri:
Lori ajọsepọ rẹ pẹlu ajijagbara fun ilẹ Igbo, Nnamdi Kanu, Sunday Igboho salaye pe oun kò mọ Nnamdi Kanu rí rara, bẹẹ ni ko si ajọsepọ kankan laarin awọn.
"Mo kọ ila soju, ọmọ Yoruba ni mi, mo maa n dọbalẹ ki awọn iya ati baba mi ni, èdè àti àṣà emi ati Kanu kò papọ rara.
Koda, ako sọrọ si ara wa ri, kò sì sí ajọseps kankan pẹlu emi ati Kanu rara.
Lakota, Igboho tun leri leka pe oun si duro lori ipinnu oun pe awọn ọdaran Fulani gbọdọ fi ilẹ Yoiruba silẹ ni, ki alaafia le jọba, ki oun to sinmi.