You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Imo ESN-Soldiers Crisis: Gómìnà Uzodinma kéde kónílé ó gbélé ní Orlu
Awọn ọmọ ikọ alaabo Eastern Security Network, ESN atawọn ọmọogun Naijiria gbe ina woju ara wọn nilu Orlu ni ipinlẹ Imo, nigba ti eruku rẹ yoo si fi rolẹ, ẹmi eeyan ti bọ, ọpọlọpọ lo si tun fara ṣese.
Eyi lo mu ki gomina ipinlẹ naa, Hope Uzodinma gbe aṣẹ konile o gbele kalẹ laarin agogo mẹfa owurọ si mẹfa irọlẹ, kaakiri gbogbo ijọba ibilẹ to wa lagbegbe Orlu.
Awọn agbegbe ti ọrọ naa kan ni Orlu, Orsu, Oru East, Oru West, Ideato North, Ideato South, Njaba, Isu, Nwangele ati Nkwerre.
- Sunday Igboho yarí lórí àwọn ‘ọ̀rọ̀ ìbajẹ́’ tí Babafemi Ojudu kọ nípa rẹ̀
- Àwọn jàǹdùkú yìnbọn sókè lọ́pọ̀ ìgbà kí wọn tó jó ilé Sunday Igboho - Ọlọ́pàá Oyo
- N kò le ṣàtìlẹyìn fún arúfin láti tán ìṣòro ètò ààbò - Seyi Makinde
- Àwọn ọ̀tá kan ń lo ìwà akọni Sunday Igboho láti bà mí lórúkọ jẹ́ - Gani Adams
- Kìí ṣe àgbẹ̀ nìkan ni ọ̀daràn darandaran n pa, wọ́n n pa àwa Fulani nàá - Ààrẹ Miyetti Allah
- Orí mi wú báwọn oríadé ṣe ní kò sí ààyè mọ́ láfi fi ọmọ Yorùbá ṣètùtù Nàìjíríà - Sunday Igboho
- Bukola Saraki sọ̀rọ̀ sókè lórí ìgbésẹ̀ Sunday Igboho
- Afurasí Fulani daran-daran fi ìbọn fọ́ ìka obìnrin kan lójú pópó
- Sunday Igboho sọ̀rọ̀ fún ìgbà àkọ́kọ́ lẹ́yìn àbẹ̀wò rẹ̀ sí Igangan
Eyi n waye lẹyin ti fidio wahala to ṣẹlẹ laarin awọn ọmọ ẹgbẹ agbebọn ESN naa atawọn agbofinro lu igboro.
Gomina Uzodinma ṣalaye ninu atẹjade kan pe, alaafia ti pada jọba lagbegbe Orlu bayii lẹyin ti wọn ko awọn agbofinro lọ sibẹ.
Oniruru iroyin lo n tẹ ileeṣẹ BBC lọwọ lori ohun gan to fa wahala naa; bi awọn kan ṣe n sọ pe laarin awọn ọmọ ẹgbẹ IPOB atawọn ologun ni laasigbo naa ti waye.
Amọ awọn eeyan miran n sọ pe awọn ole lo n ṣọṣẹ.
Gomina ipinlẹ naa ti ke sawọn agbofinro lati ṣawari awọn to wa nidi rukerudo naa.
Bi wahala naa ṣe bẹrẹ:
Awọn ileeṣẹ iroyin abẹle kan ṣalaye pe, lọjọ Ẹti ni itaporogan ibọn yinyin ti kọkọ bẹrẹ laarin awọn ologun atawọn ọmọ ikọ Eastern Security Network [ESN] ti Nnamdi Kanu gbe kalẹ laipẹ yii.
Iroyin tun sọ pe ilu Okporo lagbegbe Orlu ni wahala naa ti bẹ silẹ, ko si din ni ile marun un, to fi mọ awọn ṣọ̀ọṣi
Blessed Holy Trinity Sabbath Mission, ni ijọba ibilẹ Orlu, ti wọn dana sun.
Bakan naa, ni iro ibon tun dun lakọlakọ lagbegbe Bank Road, Orlu lọjọ Aje,
ti ipaya si n jọba lagbegbe naa bayii.