Kwara accident: Èèyàn mẹ́tàdínlógún(17) kú nínú ìjàmbá ọkọ̀ bọ́ọ̀sì lópòpóónà Jebba, ẹnìkan mórí bọ́

Agba adura ni Yoruba maa n gba pe a o ni rin lọjọ ti ebi n pa ọna.

Eeyan mẹtadinlogun lo jona raurau ninu ijamba ọkọ ero to ṣẹlẹ lopopona Bode-Saadu si ilu Jebba nipinlẹ Kwara lọjọ Abamẹta.

Awakọ ero Toyota naa ni a gbọ pe ko le dari ọkọ ọkọ naa mọ lẹyin to ti gbiyanju lati ya ọkọ akẹru to ko ata ati ọkọ ajagbe kan to wa niwaju rẹ.

Eleyi lo jẹ ki ọkọ bọọsi Toyota naa lọ fori sọ ọkọ ajagbe mii to n bọ lati ọna Jebba, lẹyin naa ni ina sọ!

Loju ẹsẹ naa ni eeyan mẹtadinlogun gbẹmi mi nibi ijamba ọhun ṣugbọn ori ko ẹnikan yọ nibẹ lai farapa rara.

Agbẹnusọ ileeṣẹ panapana ipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Hassan hakeem Adekunle lo fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ ninu atẹjade kan to ṣọwọ sawọn akọroyin.

Ọgbẹni Adekunle gbadura pe ki Eleduwa tu awọn ẹbi awọn eeyan to padanu ẹmi wọn ninu.

Ọga agba ileeṣẹ panpana ipinlẹ Kwara, CFO Falade Olumuyiwa John rọ awọn awakọ lati maa tẹẹ jẹjẹ nitori ẹmi o laarọ.