Ìgbà ọ̀tun! Lampard kó ìyà lọ, Tuchel kó ire de Chelsea

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Igba kan n lọ, igba kan n bọ, aye duro titi lae.
Eyi lo difa akọnimọọgba Chelsea tẹlẹri, Frank Lampard ti o ti idi itan bayii ni ẹgbẹ agbabọọlu naa.
Olori ẹgbẹ agbabọọlu naa, Roman Abramovich jawe gbẹle ẹ fun Lampard lẹyin ti nkan ko ṣẹnu 're mọ fun Chelsea ninu awọn ifẹsẹwọnsẹ ti wọn n kopa ninu rẹ.
- Ẹ̀yin aláboyún, ẹ pe ọkọ yín síbí láti wá kọ́ṣẹ́ nípa wíwẹ ìkókó- Nọ́ọ̀si Tolu Agbẹ̀bí
- Abdullahi, Ẹni ọdún 52 rí ẹ̀wọ̀n he nítorí pé ó jí fóònù méjì gbé ní Abeokuta
- Òfin kóńlé-ó-gbélé gbòde nílùú Igangan lórí ẹ̀rù pé Fulani le k'ógun wá lẹ́yìn ìkọlù Igboho
- Èèyàn mẹ́tàdínlógún(17) jọ́ná ráúráú nínú ìjàmbá ọkọ̀ bọ́ọ̀sì lópòpóónà Bode-Saadu sí Jebba
- Ta bá gba Seriki Fulani padà sí Igangan, a fi ọwọ́ ara wa, pa ara wa ni - Aráàlú
- Ẹ yé ṣí ìhòhò ara yín síta lórí ayélujára torí ‘Silhouette Challenge’ - Adeboye
Ṣugbọn ni bayii, omi tuntun ti ru, ẹja tuntun si ti wọ lẹgbẹ agbabọọlu Chelsea lẹyin ti Tomas Tuchel di akọnimọọgba tuntun fun Chelsea.
Ọmi ni Chelsea gba pẹlu Wolves ninu ifẹsẹwọnsẹ akọkọ ti Chelsea ti gba lẹyin ti Tuchel de.
Amọ, ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea fakọyọ lọjọ Aiku, lẹyin ti bo Burnley mọlẹ nile wọn pẹlu ami ayo meji sodo.
Balogun ikọ Chelsea, Cesar Azpilicueta lo gbayo akọkọ sawọn fun Chelsea ki Marcos Alonso to fọba lee nigba to ku diẹ ki ifẹsẹwọnsẹ naa pari.
Ipo kẹsan ni Chelsea wa bayii lori tabili idije English Premier League.












