You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Transfer deadline day: Man United ra arúgbó ọjọ́ Cavani, Arsenal bínú ra Partey, Walcott padà sí ẹsẹ àárọ̀
Ẹni to ba foju ana wo oku, ẹbọra ni yoo bọ oluwa rẹ laṣọ. Ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal ya agbado ha sawọn ololufẹ ere bọọlu lẹnu lẹyin ti wọn ra agbabọọlu aaringbungbun Thomas Partey lati Atletico Madrid.
Lọjọ karun un oṣu kẹwaa ọdun 2020 ti ọja kata-kara kasẹ nlẹ ni Arsenal ra Partey ni miliọnu marundinlaadọta owo pọun.
Partey to jẹ ọmọ ọdun mẹtadinlọgbọn kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ liigi La Liga marun din logoji, o si gba goolu mẹta sawọn fun Atletico ni saa bọọlu to lọ.
- Ayé má níkà o! Tottenham ya aṣọ iyì mọ́ Manchester United lára nírọ̀lẹ́ ọ̀jọ́ ìsinmi
- Dákúdájí Chelsea bínú já òrùlé Stamford Bridge lé Crystal Palace lórí
- Agbẹjọ́rò fún Sotitobire yọ ọwọ́ nínú ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ lónìí!
- Ààrẹ Donald Trump ti padà sí ilé ìjọba lẹ́yìn ọjọ díẹ̀ tó lùgbàdì ààrùn coronavirus
- Ẹ̀yin olùkọ́, ìlànà àkànṣe owó oṣù tuntun dé fún yín
- Ẹ̀wọ̀n ni wàá gbẹ̀yìn sí, kò sí bóo ṣe dọ́gbọ́n tó - Seyi Makinde wa ègúná ọ̀rọ̀ lé Fayose
Partey to jẹ ọmọbibi orilẹede Ghana gba ife ẹyẹ Europa League ati Super Cup ọdun 2018 pẹlu Atletico nigba to wa nibẹ.
Ẹwẹ, agbabọọlu Arsenal, Lucas Torreira lo rọpo Partey ni Atletico Madrid lẹyin to darapọ mọ wọn fun ọdun kan.
Torreira lanfaani lati pada si ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal lẹyin ọdun kan.
Edinson Cavani dero Manchester United
Yoruba bọ, wọn ni bi a ko ba ri adan, a mọ fi obẹ ṣe ẹbọ. Bayii gan an ni ọrọ ṣe ri pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United ninu ọja kata-kara awọn agbabọọlu to kasẹ nlẹ lọjọ Aje ọjọ karun un oṣu kẹwaa ọdun 2020.
Agbabọọlu Borusia Dortmund Jadon Sancho ni Man United kọkọ le lati ra ṣugbọ ko ri ra nitori owo gọbọi ni Dortmund gbe le lori.
Eyi lo jẹ ki man U lọ fun ẹleṣẹ ayo ẹgbẹ agbabọọlu PSG tẹlẹ, Edinson Cavani, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn.
Ọta le lugba o din mẹwaa ẹgbẹrun owo pọun(£250,000) ni Cavani yoo maa gba ni Manchester United.
Aṣọ gbajugbaja Nọmba 7 tawọn agbaọjẹ agbabọọlu to ti ṣoju Man United tẹlẹ ri ni Cavani yoo maa wọ.
Theo Walcott pada si Southampton
Ẹlẹsẹ ayo Theo Walcott ti pada si ẹgbẹ agbabọọlu Southampton lati Everton fun ọdun kan.
Walcott pada si Southampton lẹyin ọdun mẹẹdogun to fi ẹgbẹ agbabọọlu silẹ darapọ mọ Arsenal.
Ọdun 2018 ni Walcott fi Arsenal silẹ lọ Everton lẹyin ti wọn ta a ni ogun miliọnu pọun.
Walcott ọmọ ọdun mọkanlelọgbọn ṣalaye pe awọn ẹgbẹ agbabọọlu mii fẹ ra oun amọ oun pinnu lati pada si ẹsẹ aarọ ni Southampton.
Lọdun 2005 ni Walcott bẹrẹ si ni ṣoju Southampton nigba to pe ọmọ ọdun mẹrindinlogun.