Chelsea vs Crystal Palace: Chelsea bínú gbẹ̀san ìyà Tottenham lára Crystal Palace

Akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea, Frank Lampard ti fi idunnu rẹ han pẹlu bi wọn ṣe na Crystal Palace lalubami pẹlu ami ayo mẹrin si odo.

Lampard ni aṣeyọri awọn ko ṣẹyin agbabọọlu tuntun, Ben Chilwell ti wọn ra fun miliọnu marundinlaadọta pọun.

Chilwell to jẹ ẹni ọdun mẹtalelogun lo gba bọọlu wọ inu awọn, nigba ti Zouma ṣe iranwọ fun goolu keji, Jorginho gba penariti wọ inu awọn ni igba kẹta ati ikẹrin.

Amọ, Frank Lampard ti rọ awọn agbabọọlu rẹ lati farabalẹ nitori ere ṣẹṣẹ bẹrẹ ni.

Laipẹ yii ni Liverpool lu Chelsea ni alubami, ko to di wi pe wọn gberasọ pada.

Bakan naa naa ni Everton naa Brighton ni ami ayo mẹrin si meji , nibi ti Rodriguez ti gba ami ayo meji wọ ni awọn, ti CalverLewin ati Mina naa gba bọọlu wọ inu awọn.