Adesanya UFC253: Wo ìlúmọ̀ọ́ká akànṣẹ́ mẹ́ta ọmọ Nàìjíríà tó ń ṣe bẹbẹ lágbàáyé

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Bi ọmọ ẹni ba daa, ẹ jẹ ki a wi, kii se pe a kuku fẹ fi ṣe aya ni.

Awọn ọmọ Naijiria to n ṣe bẹbẹ lagbo eṣẹ kikan lagbaaye lo bi ọrọ yii.

Mẹta ni wọn, awọn naa si ni, Anthony Joshua, Israel Adesanya ati Kamaru Usman.

Lootọọ oke okun ni awọn mẹtẹẹta fi ṣe ibugbe, amọ ko si ẹni to gbagbe orilẹede Naijiria gẹgẹ bi orirun wọn, ninu awọn mẹtẹẹta.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ẹ jẹ ki a wo bẹbẹ tawọn ọmọluabi mẹtẹẹta ọmọ Naijiria yii ṣe lagbaaye:

Israel Adesanya - Igba ogun lo ti figa gbaga, ti ko si fidi rẹ́mi ninu ikankan

Ko si ẹni to le kọ iyan Israel Adesanya kere lagbo ẹṣẹ kikan ti UFC, ti wọn tun maa n pe ni MMA.

Ilu Auckland lorilẹede New Zealand lo fi ṣe ibugbe, amọ ilu Eko ni wọn bi Israel si lọjọ kejilelogun oṣu keje ọdun 1989.

Igba ogun ni Adesanya ti fija pẹẹta pẹlu oriṣiiriṣii awọn alatako, ṣugbọn gbogbo wọn lo la lalubolẹ bi ilu bẹmbẹ.

Koda, o tun ṣẹṣẹ fakọyọ ninu ija to ja kẹyin ni, nibi to ti ṣe Paulo Costa bi ọsẹ ti n ṣe oju, ninu ija to waye niluu Abu Dhabi lorilẹede UAE laarọ lọjọ Aiku.

Ipele keje ni wọn ṣẹṣẹ de nigba ti Israel ti lu Costa, ti ori rẹ si bẹjẹ eyi to mu ki alakoso ija gbọwọ rẹ soke pe, o ti jawe olubori.

Lọwọ yii, Israel ni igbanu ''UFC Middleweight'' wa lọwọ rẹ lagbaaye.

Kamaru Usman - Ninu ija mẹtadinlogun, o fidi rẹmi ninu ẹyọ kan

Kamaru Usman naa, tii ṣe ọmọbibi orilẹede Naijiria, jẹ akọni abẹṣẹ ku bi ojo lagbo ija MMA.

Orilẹede Amẹrika lo fi ṣe ibugbe, amọ ilu Auchi nipinlẹ Edo ni wọn ti bi Usman, lọjọ kọkanla oṣu karun un ọdun 1987.

Igba mejidinlogun ni Usman ti ja, mẹtadinlogun lo ti jawe olubori, ti o si fidi rẹmi ninu ọkan ṣoṣo ninu wọn.

Ọjọ kejila oṣu keje ọdun 2020 ni ija to kopa ninu rẹ kẹyin waye, ninu eyi to ti lu Jorge Masvidal niluu Abu Dhabi.

Usman ni igbanu ''UFC Welterweight'' wa lọwọ rẹ bayii.

Anthony Joshua - Igbanu mẹta lẹka ẹṣẹ kikan to lami laaka lo wa lo lọwọ rẹ nikan

Ti a ba n sọrọ awọn afi ẹṣẹ ku bi ojo lagbaaye, ọrọ ko tii tan ti a ko ba darukọ Anthony Oluwafemi Joshua.

Niluu Watford lorilẹede England, ni wọn ti bi Joshua lọjọ kẹẹdogun oṣu kẹwaa ọdun 1989, amọ bi iṣu lo maa jẹ orilẹede Naijiria lẹnu.

Koda, o ti figba kan gbe ilu Eko ri nigba to n dagba.

Joshua ti gba oriṣiiriṣii ami ẹyẹ ninu ẹṣẹ kikan lagbaaye, to fi mọ ami ẹyẹ wura ninu idije ''Olympics'' ọdun 2012.

Joshua ti fẹṣẹ yanju awọn ilumọọka akanṣẹ bi Wladimir Klitschko, Charles Martin, Joseph Parker, Alexander Povetkin ati Andy Ruiz Jr.

Igbanu mẹta lẹka ẹṣẹ kikan to lami laaka lo wa lo lọwọ AJ nikan.

Oun ni igbanu IBF, IBO, WBA ati WBO ''heavyweight'' wa lọwọ rẹ bayii.

Káre akọni ọmọ Yoruba! Israel Adesanya fi ẹ̀ṣẹ́ fọ́ Paulo Costa lójú

'Misita Alagidi, emi leleyi!' ni gbolohun ti Israel Adesanya fi da awọn alatako rẹ lohun lẹyin to da bantẹ iya fun Paulo Costa ninu ija wọn to waye ni Dubai.

Isọri keji ija naa ni Adesanyta ti rọjo ẹsẹ lu Costa ti adari ija naa si bọ si aarin wọn lati pari rẹ ni kiakia.

Ni bayi, Adesanya ṣi ni o jẹ olubori Middle Weight Champion of the World.

Loju opo Twitter awọn ọmọ Naijiria to fi mọ Minisita feto ọdọ ati idaraya Sunday Dare ti n ki ku orire ija naa

Mo ṣetán láti ṣe Paulo Costa bí ọṣẹ sẹ ń ṣojú lọ́la- Israel Adesanya

Ọjọ nii pẹ, ipade kii jian. Ọjọ Aiku tii ṣe ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kẹsan an ọdun 2020 ni ajijakandi ọmọbibi orilẹede Naijiria to jẹ aṣaaju ninu ija UFC, Israel Adesanya to yoo koju Paulo Costa ọmọ ilẹ Brazil.

Faabada! Ẹyin ologinni ko gbọdọ balẹ. Adesanya ko ti fidi rẹmi ri lati igba to ti di agbaọjẹ lagbo UFC.

Ija MMA mọkandinlogun ni Adesanya ti kopa ninu rẹ ti o si jawe olubori ninu gbogbo wọn, nigba ti alako rẹ, Costa ko tii fidi rẹmi ninu ija MMA mẹtala to ti ja.

Ilu Abu Dhabi, United Arab Emirates lawọn mejeeji yoo ti waako lọjọ Aiku.

Nigba ti wọn n tahun si ara ṣaaju ija ọjọ Aiku, Costa oun yoo gbe Israel tọrọ ba doju rẹ tan nitori ko lara.

Amọ ile lo kuku ba Adesanya naa, oun naa sọ pe oorun ti ko si Costa loju ohun lo si n ṣakoba fun un.

Adesanya ni ti oun ba le ki Costa lọrun mọlẹ pẹrẹ, o ni ọrun naa ko tun jẹ tirẹ mọ.

Israel sọ pe o ṣe oun bi ki ija naa ti bẹrẹ nitori oun ko le duro mọ lati da ẹṣẹ bo Costa lori.

Igba mẹrinla ni Adesanya ti lu alatako rẹ lalubami ti wọn maa n pe ni TKO ninu ija mọkandinlogun to ti ja.