You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Alaafin Oyo: Kíni 'Ẹ̀lẹ̀ daddy' Olorì Abbey Adeyemi ṣe tí ojú òpó ayélujára rẹ̀ fi ń yeruku lálá?
Lai si ani-ani, Olori Abbey jẹ ọkan lara awọn ''Ẹ̀lẹ̀ Daddy, afẹ́fẹ́ tí Alaafin Oyo, Oba Lamidi Olayiwola Adeyemi fi n mi.
Lọjọ Abamẹta, ọjọ kẹrinlọgbọn, oṣu Kẹsan, ọdun 2020 ni Olori fi oriṣiriṣii fọto rẹ ati ti Alaafin pẹlu pẹlu ọmọ ti Eleduwa fi jinki wọn si oju opo Instagram rẹ.
Lẹyin naa, ọpọ eeyan bẹrẹ si ni beere wi pe ki ni Olori n ṣe gan an?
- Ìkébé mi tóbí ju ohun tí mo lè dọwọ́ bò lọ, n kìí fí ṣakọ- Nkechi Blessing
- Àwọn onílù mí ló ń tú àṣírí ìkà èèyàn tó bá wọ ààfin mi - Aláàfin
- Wò ó bí Alaafin àti aya àkọ́fẹ́ rẹ̀, Olorì Abibat ṣe pàdé ní èwe
- Oluwo kọ̀ láti sọ̀rọ̀ lórí àwọn afọbajẹ tó fẹ́ yọ ọ́ nípò, aráàlú fọ́n síta láti fẹ̀hónú hàn
- Ìdùnnú subú layọ̀ nípìnlẹ̀ Ọyọ́, àwọn tó dé láti Lebanon sọ ọmọ wọn ní Seyi
- Mo ṣetán láti ṣe Paulo Costa bí ọṣẹ sẹ ń ṣojú lọ́la- Israel Adesanya
- Èèmọ̀! Àwọn adigunjalè yabo ṣọ́ọ̀ṣì, fipá bá obìnrin kan lòpọ̀, yìnbọn fún òmííràn
Amọ, ninu ohun to kọ sori awọn to fi sori awọn fọto, Olori Abbey kọkọ gboṣuba rabandẹ fun Eleduwa fun ore-ọfe to fun oun.
O dupẹ fun Ọlọrun fun ọpọlọpọ ibukun to fi fun oun lati igba ti oun ti wa loke eepẹ.
Lẹyin naa lo bẹrẹ si ni dupẹ ni mẹsan an mẹwaa lọwọ olowo-ori rẹ, Alaafin Oyo.
Olori Abbey ni oun ko le ṣalai dupẹ lọwọ Iku Baba Yeye fun ifẹ ti ko ṣe fẹnu sọ to ni si oun, fun ọrọ ti oun n jẹ anfaani rẹ ati fun idunnu ati ayọ to n ri lara Oba Adeyemi.
''Kabiesi, lai si iranwọ yin ati ifẹ ti ko lẹgbẹ ti ẹ fihan si mi, ko ba ti si ẹni to n jẹ emi,'' Olori Abbey lo sọ bẹẹ.
O ni lai si ore-ọfẹ ti oun n ri jẹ lara Alaafin ni, oun ko le di iru obinrin t'oun da lonii.
Olori Abbey ni ọpẹ oloore, adaadatan ni, o ni lailai l'oun yoo maa dupẹ lọwọ Ọba Lamidi Adeyemi.
Ni ipari ọrọ rẹ ni Olori Abbey ki ara rẹ ku ayẹyẹ ọjọ ibi, o gbadura pe ki Eleduwa fi ẹmi gigun ati ayọ jinki oun.