You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ighalo Transfer Fee: Ilé aṣòfin Osun ní òun kẹ́ẹ́fín pé àpò àdáni ní owó náà wà
Ile Igbimo Asofin ipinlẹ Osun ti bẹrẹ iwadii lori ẹgbẹrun mẹwaa pọnun, to kan ẹgbẹ agbabọọlu Osun United, lara owo adehun to gbe Odion Ighalo lọ si Manchester United.
Idi ni pe ile asofin kẹfin pe owo naa ti wọ apo aladani kan.
Ẹgbẹ agbabọọlu ipinlẹ Osun ọhun, ti o n jẹ Prime FC, ni Ighalo ti gba bọọlu kẹyin ko to lọ si ilẹ okeere, nibi to ti darapọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu Norwegian kan ni Lyn Oslo lọdun 2007.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- PDP àti APC fi ìbọn dárà l'Ondo, ọ̀pọ̀ èèyan farapa, àìmọye dúkìá ṣòfò
- "Dípò ìnákúnàá lórí ìgbéyàwó ọmọ mi, mo lò owó fún ìgbéyàwó ọmọ òrukàn mẹ́tàlá"
- Àwàdà kẹríkẹrì nígbà táwọn olùdíje ààrẹ́ Amerika méjì kọjú ìjà síra wọn
- Ìjọba àpàpọ̀, jọ̀ọ́ máṣe yẹ̀ lórí àdéhùn rẹ fẹ́gbẹ́ òṣìṣẹ́ - Ile aṣojú-ṣòfin
- Ọgọ́rin arìnrìnàjò tó padà wá sí Nàìjíríà ló ní Coronavirus - PTF
- Wo iye tí ìjọba yóò gbà lọ́wọ́ Laycon gẹ́gẹ́ bí owó orí ẹ̀bùn BBNaija tó jẹ
- N kò mọ ẹni tó fẹ́ gba ìyàwó mi, àmọ́ wọn máa ń sọ pé ó rẹwà - Mike Bamiloye
Ọkan lara awọn to sun mọ kọmisọna to n ri si ọrọ ere idaraya Yemi Lawal, wa lara awọn ti wọn pe si ipade ni ile igbimọ asofin fun iwadii ọrọ naa lọsẹ to kọja.
Bakan naa, ni awọn miran to tun wa nibi ipade ti alaga igbimọ ile lori ọrọ ere idaraya, Abdullahi Adegbile pe ni awọn Alakoso ẹgbẹ agbabọọlu Osun United.
Akọwe ẹgbẹ agbabọọlu naa, Kabiru Adekunle ati adele adari igbimọ alabojuto ere idaraya ni Osun, Rotimi Oludunmoye naa peju si bẹ pẹlu.
Bakan naa ni wọn darukọ Gbenga Ololade to jẹ adari Prime FC nigba naa, gẹgẹ bi ọkan lara awọn to mọ nipa owo ti wọn fi ra Ighalo lọ nigba naa.
Alaga igbimọ ile asofin fun ere idaraya, Adegbile salaye pe, igbimọ naa ko ti pari iwadii wọn lori ọrọ naa.
"Lẹyin ti a gbọ iroyin, a pe gbogbo awọn ti ọrọ kan. Lẹyin iwadii lẹkunrẹrẹ, mo fi n da yin loju pe a sọ abajade nkan to ṣẹlẹ ni gbangba, a o si tun wọn pe ninu ọsẹ yii."
Ọkan lara awọn oṣiṣẹ Osun United ti ko fẹ ki orukọ oun jade, sọ fun ile iṣẹ iroyin Punch pe, ẹgbẹrun mẹwaa pọun wọle sinu akanti banki Access Osun United, ninu oṣu kaarun ọdun.
O fi kun pe, aarẹ ẹgbẹ agbabọọlu naa tẹlẹ ati adari ile iṣẹ to n ri si ọrọ ere idaraya lọwọ, nikan ni wọn le buwọlu iwe owo akanti ọhun.
O ni ipade pẹlu ile igbimọ asofin ko tii ni iyanju.
"Ko si aniani, owo wọle si apo owo Osun United, sugbọn wọn ko tilẹ bun awọn alaṣẹ Osun United to ni akanti naa leti rara.
"Alaga igbimọ naa ni ki a tun pada wa fun ipade miran lori ọrọ ọhun ni ọjọ Eti to kọja, sugbọn o ṣeni laanu pe, awọn ọmọ ile igbimọ asofin ko yọju.
Ololade, to jẹ adari Prime FC lasiko naa salaye pe, ile igbimọ asofin wa lori ọrọ naa ati pe, wọn ti kilọ fun awọn pe ẹnikẹni ko gbọdọ ba awọn oniroyin sọrọ, titi ti iṣẹ iwadii yoo fi pari.