Marriage in Zamfara: Sẹ́nétọ̀ Kabiru Marafa ní àìsí ìrànwọ́ fọ́mọ òrukàn ló jẹ́ kí òun di ẹrù ìyàwó fún wọn

Sẹ́nẹ́tọ̀ nígbà kan rí láti ìpínlé Zamfara, tí ṣe ìrànwọ́ ẹrù ìyàwó fún ìyàwó mẹ́tàlá kan tí wọ́n jẹ́ ọmọ òrùkan ní Gusau, olú ìlú ìpínlẹ̀ Zamfara.

Inú ìdùnnú ni àwọn ọmọ òrukàn yìí wa nítorí pé, wọn kò lérò pé wọn yóò rí irú ẹrù ìyàwó tí wọ́n rí lọ́fẹ̀ẹ́ yìí dì, gẹ́gẹ́ bíi ọmọ òrukàn.

Sẹ́nẹ́tọ̀ Kabiru Marafa sọ pé, òun ṣe ìrànwọ́ yìí ni nítorí pé òun wòye bí àwọn ọmọ tí àwọn agbébọn sọ di ọmọ òrukan ṣe pọ̀ tó ní Ìpínlẹ̀ náà.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Sẹ̀nẹ́tọ̀ ọ̀hún sọ pé: "Ní Ìpínlẹ̀ Zamfara báyìí, àwọn ọmọ orukan yóò tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́ta, tó sì jẹ́ pé àwọn ọmọ òrukàn yìí ò sì ní olùrànlọ́wọ́.

O ni àyàfi ẹni tó bá wo ti Ọlọ́run, tí ó ríi pé ó yẹ kó ràn wọ́n lọ́wọ́ "

Ó tún fi kún un pé: "Nígbà tí àsìkò ìgbéyàwó ọmọ mi tó, mo wàásù fún un pé kó má jẹ́ kí wọn nà owo ni ìnákúnàá níbi ètò ìgbéyàwó rẹ̀, nítorí a le fi owo naa ṣe iranwọ fun àwọn aláìní.

Mo sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run pé ó fagilé àwọn ohun to le gbọn owo lọ níbi ìgbéyàwó rẹ̀, tó sì lọ owó ọ́hún lati fi ran àwọn ọmọ òrukàn mẹ́tàlá di ẹrù ìyàwó wọn."

Ó ní àwọn ọmọ òrukàn pọ̀ tí wọ́n ti dájọ́ ìgbéyàwó sọ́nà, ṣùgbọ́n tí wọ́n ń sún ọjọ́ náà sí wàjú nítorí pé kò sí owó.

"Eyí ló fà á tí mo fi ríi pé ó tọ́ kí n sa àwọn tí wọ́n ti dájọ́ ìyàwó wọn tipẹ́ nítorí kí n lè bá wọn di ẹrù ìyàwó kí wọ́n leè báà rọ́nà lọ."

Wọ́n sún ìgbéyàwó sí wájú nítorí àìní.

Sẹ́nẹ́tọ̀ Marafa sọ pé, ọmọbìnrin kan wa tí wọ́n sún ìgbéyàwó rẹ̀ sí wájú ní ẹ̀ẹmẹ̀sán nítorí àìní.

"Tí a bá sì ronú nípa ìgbéyàwó ọhun, ọpọ nǹkan tí wọ́n ó nàá kò tó nǹkan, ṣùgbọ́n wọn kàn ń sún ìgbéyàwó náà sí wájú ni nítorí jíjẹ ọmọ òrùkàn àti àìní.

Ní àwọn gbèríko, ẹ ó ríi pé wọn ń sún ìgbéyàwó sí wájú nítorí àìní, àwọn ènìyàn wa kìí sìí rán irú àwọn ọmọ òrukàn yìí lọ́wọ́.

Eléyìí ló fà á tí mo fi ṣe ìrànlọ́wọ yìí, a ó sì tẹ̀síwajú láti máa wá irú àwọn ọmọ òrukàn yìí jáde, tí a ó ṣí mà ràn wọń lọ́wọ́."

Àwọn ẹbí àwọn tí wọ́n rí ìrànwọ́ yìí gbà sọ pé, kò sí nǹkan tí àwọn lè sọ lóríi bí wọ́n ṣe báwọn nu omijé àwọn nù, yatọ si pe ki awọn dupẹ.

Wọn ni tẹlẹ, awọn ko ri igbeyawo ọmọ wọn ṣe nitori àìní owó tí wọn yóò fi di ẹrù ìyàwó fún wọn, eléyìí tí wọ́n tí bà wọ́n ṣe báyìí.