You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Mane dá iná yá Kepa lábẹ́ lẹ́ẹ̀mejì bí Liverpool ṣe lu Chelsea lálùmọ́lẹ́ bíi bẹ̀m̀bẹ́.
Nkan ti baba fi ju ọmọ lọ ni ẹgbẹ agbabọọlU liverpool fi ọrọ ṣe pẹlu bi wọn ṣe din dundun iya goolu meji si odo fun Chelsea.
Ifẹsẹwọnsẹ naa to waye nile Chlesea jẹ akọkọ ti wn yoo gba nibẹ lati igba ti saa bọọlu tuntun ti bẹrẹ.
Sadi Mane agbawaju Liverpool lo jẹ goolu mejeeji to mu ki Liverpool gunke si ipo kẹẹta lori afara Liigi.
Chelsea wa ni ipo ikẹwa bayi ti Arsenal asi n tọ Everton lẹyin ni ipo keji.
Aṣiṣe meji lo ṣokunfa ifidirẹmi Chelsea ninu ifẹsẹwọnṣẹ naa.
Akọkọ ni ti Christensen to gba kaadi pupa lẹyin to fa Sane titi to fi ṣubu lasiko to n gbiyanju lati lọ jẹ ni ile Chelsea.
Nitori eyi, eeyan mẹwa dipo mọkanla ni Chelsea fi gba ifẹsẹwọnsẹ naa ti eleyi si fun Liverpool lagbara lati wọle siwọn lara.
Aṣiṣe ẹlẹẹkeji ni ti aṣọle Chelsea Kepa Arizzabalaga to jẹ ki Sane gba goolu keji wọle.