Manchester City vs Manchester United: Man United fọ́ Man City lẹ́nu yánkanyànkan mọ́lé

Igba la a ni ẹnikan ko le lo ile aye gbo, bayii lọrọ ri fun ẹgbẹ agbabọọlu Manchester City ti ife ẹyẹ idije Premier League wa lọwọ wọn.

Orogun wọn ti wọn jọ wa niluu kan naa, Manchester United lo fiya ajẹtun iya jẹwọn lairo tẹlẹ nile wọn.

Marcus Rashford lo gbayo alakọkọ wọle fun Man United nigba ti ẹrọ VAR fun wọn ni pẹnariti.

Ere bọọlu mọ Man City loju nigba ti Anthony Martial gba goolu keji sawọn Man City, lo ba ayo meji sodo ti wọn fi n siwaju wọn.

Nicolas Otamendi dayo kan pada, amọ ẹpa ko boro mọ fun Man City.

Esi ifẹsẹwọnsẹ yii jẹ iyalẹnu fun ọpọlọpọ awọn ololufẹ ere bọọlu nitori ko si ẹni to le pe Man U le na Man City mọ le.

Àkọ́já ewé akọ́nimọ̀ọ́gbá fìdíhẹẹ́ Everton, ìyà ló bádé fún Chelsea

Ilẹ n yọ gbe Chelsea ṣubu yakata ni Goodison Park ti ṣe papa iṣere Everton

Ẹgbẹ agbabọọlu Everton ṣẹṣẹ le akọnimọọgba wọn Marco Silva lọ ni, ki wọn to yan Duncan Ferguson gẹgẹ bi akọnimọọgba fidihẹ.

Iyalẹnu lo jẹ pe iṣẹju marun un ti wọn bẹrẹ ifẹsẹwọnsẹ naa ni Richarlison gbayo kan wọle Chelsea lairo tẹlẹ.

Ka to wi, ka to fọ, Dominic Calvert-Lewin gbayo keji sawọn Chelsea lẹyin iṣẹju mẹrin ti ipele keji ere bọọlu naa bẹrẹ.

Mateo Kovacic dayo kan pada fun Chelsea, amọ Calvert-Lewin gbayo kẹta wọle fun Everton, ni okote ba bo niru fun Chelsea.

Lẹyin ọ rẹyin, ami ayo mẹta sẹyọkan ni Everton fi gbo ewuro soju Chelsea