FIFAWWC -Ọ̀rọ̀ ti yanjú dé ibì kan lórí owó àjẹmọ́nú àwọn Super Falcons

agbabọọlu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ko si iṣẹ ajé tó rọrun ni ọrọ awọn Super Falcons

Awọn agbabọọlu obinrin Naijiria joye Akintọla taku ni France.

Ẹgbẹ́ agbabọọlu Super Falcons to ṣoju Naijiria ninu idije ife ẹyẹ agbaye tawọn obinrin to n lọ lọwọ ni France ti já Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ parí, Germany di ẹrù ìyà aláwẹ́ mẹ́ta lé Najiria lórí.

Ninu idije ti ikọ agbabọọlu Germany ti fun wọn ni ami ayo mẹta si odo ni Super Falcons ti já kuro ninu idije tọdun 2019.

Kete lẹyin eyi ni iroyin gba igboro kan pé wọn ti taku sinu iyara ile itura wọn pe awọn ko ni tẹ̀ta afi ti ijọba Naijiria ba san owó ajẹmọnu awọn.

Jane Nwaeze tó jẹ agbẹnusọ fawọn ọdọbinrin agbabọọlu Naijiria ṣalaye fun BBC pe irọ ni pe awọn Super Falcons n fẹhonuhan ni France.

O ni diẹdiẹ ni awọn agbabọọlu naa n kuro nile itura ti wọn wa nitori ọtọọtọ ni wọn de si France ati pe ọtọọtọ nibi ti wọn n lọ.

Koko ti BBC fidiẹ mulẹ ni pe tootọ ni inu awọn agbabọọlu naa ko dun si aisan owo ajẹmọnu wọn bi o ti yẹ.

falcons

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọ̀rọ̀ ti yanjú dé ibì kan lórí owó àjẹmọ́nú àwọn Super Falcons

Colin Udoh to jẹ agbẹnusọ Super Eagles tẹlẹ ni ọkan lara awọn agbabọọlu naa ṣo fun oun pe awọn owo ajẹmọnu mii ti pẹ.

O ni omii wa lati idije pẹlu Gambia ati Senegal lọdun meji sẹyin.

Àkọlé fídíò, Widows Day 2019: Mo máa ń sá kiri wá owó ilé ni -Opó

Akọroyin BBC to wa pẹlu ikọ agbabọọlu naa nile itura ti wọn wa ni France sọ pe lẹyin ọpọlọpọ ipade ọrọ ti n yanju lọ.

O ni ọkan ninu awọn agbabọọlu ti ko fẹ ki wọn darukọ oun sọ pe awọn ṣẹṣẹ pari ipade pẹlu alakoso ere bọọlu Naijiria NFF ni.

Àkọlé fídíò, Florida: Ọ̀ọ̀nì àléègbà dé ba Mary lálejò lọ́gànjọ́ òru

O ni wọn ti fi da gbogbo agbabọọlu loju pe awọn yoo san ajẹmọnu naa laipẹ ki onikaluku le pada si ibudo rẹ.

Eyi kii ṣe igba akọkọ ti awọn agbabọọlu Naijiria maa fariga lori aisan owo ajẹmọnu wọn gẹgẹ bi ajọ NFF ṣe ṣeleri fun wọn.

Àkọlé fídíò, Ebola Virus: ìdí tí Ebola fi ń tàn kálẹ̀

Bẹẹ, awọn Super Falcons naa ti joye Akintọla taku yii lọdun 2016 ni Cameroon ati nigba ti wọn fẹhonuhan ni Abuja lẹyin idije pe wọn ko san awọn owó ajẹmọnu awọn.

Bayii, wọn ni ajọ NFF ti gba lati san owo ajẹmọnu wọn laiyọ ti kikopa ninu ife ẹyẹ agbaye ti FIFA san silẹ.