Ajọ FA pe Guardiola lẹjọ lori mimu oṣelu wọ bọọlu

Pep Guardiola, olukọni ẹgbẹ agbabọọlu Manchester city

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, O ti pẹ ti Pep Guardiola ti n wọ asọ ifunpa penpe lawọn ifẹsẹwọnsẹ to ti n kopa

Ọga agba ajọ to n ṣe amojuto ere bọọlu ni ilẹ Gẹẹsi, Martin Glenn ti sọọ di mimọ fun olukọni ẹgbẹ agbabọọlu Manchester City, Pep Guardiola wipe ko ṣaye apala ni ilu ọba nitorina, "ajọ naa ko lee fi aye gba awọn ami oṣelu lagbo ere bọọlu"

O ti pẹ ti Pep Guardiola ti n wọ aṣọ ifunpa penpe lawọn ifẹsẹwọnsẹ lati fi ṣe atilẹyin fun awọn oloṣelu ti wọn fi si ahamọ ni ilu Catalonia.

Loṣu to kọja, ajọ ere bọọlu nilẹ Gẹẹsi ti kọkọ f'ofin de olukọni ikọ agbabọọlu Manchester city naa lẹyin ti wọn ti faa leti lẹẹmeji.

Pep Guardiola, olukọni ẹgbẹ agbabọọlu Manchester city

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Igba meji ni wọn ti jawe ikilọ fun Guardiola

Nibi ipade apero f'awọn ajọ ere bọọlu lagbaye to waye ni ilu Zurich nibiti wọn ti jiroro lori lilo ẹrọ ayaworan oju tole-toko fun idari idije bọọlu ni ọgbẹni Glenn ti s'ọrọ yii.

"Laif'igba kan bọ ọkan ninu, ami oṣelu ni aṣọ ifunpa penpe ti o nlo, aami igbominira awọn eeyan agbegbe Catalonia ni."

Mo lee fi ọwọ ṣọya pe ọpọlọpọ awọn ọmọ orilẹede Spain atawọn ti kii ṣe ọmọ orilẹede naa ni ko f'ara mọ eyi."

Pep Guardiola, olukọni ẹgbẹ agbabọọlu Manchester city

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Ọmọ ẹkun Catalonia lorilẹede Spain ni Guardiola

Igba meji ọtọọtọ ni wọn ti fun Pep Guardiola ni ikilọ lori ọrọ yii ki wọn to kuku fẹsun kan an ni oṣu keji ọdun 2018.

Ọjọ aje, ọjọ karun oṣu kẹta ni gbedeke ti wọn fun Pep Guardiola lati wa wi awijare rẹ lori ẹsun ọhun.

Ohun to ṣ'okunfa ẹsun ọhun ni bi Pep Guardiola tun ṣe wọ aṣọ ifunpa penpe nibi ifẹsẹwọnsẹ ife ẹyẹ FA ti wọn gba pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu Wigan lẹyin ti wọn ti fidirẹmi.

Awọn iroyin ti ẹ le nifẹ si: