Ọlọ́pàá ìpínlẹ Ogun mú olùkọ́ tó fipá bá akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ ọdún mẹ́sàn-án lòpọ̀

Ileeṣẹ ọlọpaa ti mu olukọ kan, Ayobami Runsewe, ẹni ọdun marundinlọgbọn ti wọn fi ẹsun kan pe o fi ipa ba akẹkọọbinrin lopọ nilu Ago-Iwoye.

Runsewe to jẹ olukọ nile ẹkọ alakọbẹrẹ kan to jẹ aladani nilu naa, fi ẹ̀tàn tan ọmọ ọdun mẹsan-an ọhun lọ si ile rẹ to wa ni adugbo ayegbami, lẹyin ti wọn jade nile ẹkọ nibi aago mẹrin aabọ irọlẹ.

Nibẹ lo si ti fi ipa balopọ.

Ṣugbọn ọwọ tẹ afurasi naa lọjọbọ, lẹyin ti iya ọmọdebinrin naa fi ẹjọ sun ni olu ileeṣẹ ọlọpaa ni Ago-Iwoye.

Agbẹnusọ ọlọpaa nipinlẹ Ogun, SP Abimbola Oyeyemi, sọ ninu atẹjade kan lọjọ Abamẹta pe, pẹlu pátá ọmọ naa to kun fun ẹjẹ, ni iya rẹ wa si agọ ọlọpaa gẹgẹ bi ẹri.

SP Oyeyemi sọ pe Runsewe kọkọ ṣẹ́ lori ẹsun naa pe oun ko ni ohunkohun ṣe pẹlu akẹkọọ naa, ṣugbọn nigba ti ọmọ naa koju rẹ, ko ri ọrọ sọ mọ.

Ni bayii, kọmisanna ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Lanre Bankole, ti paṣẹ pe ki wọn o taari afurasi naa si ẹka to n ṣe iwadii ọtẹlẹmuyẹ lori ilokulo ọmọde.

Ẹka naa ni yoo wadii isẹlẹ yii, ti yoo si tun gbe ọrọ lọ sile ẹjọ.