You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Polygamy: Fífẹ̀ ju ìyàwó kan lọ ni àṣírí ẹ̀mí gígùn'
Àwọn oluwadii kan ni Fasiti Sheffield ni orile-ede United Kingdom, ti sọ pe fifẹ iyawo meji ni aṣiri si ẹ̀mí gigun.
Lootọ ni ọpọ ọkùnrin le ro pe iyawo kan ní wahala tiẹ, sugbọn iwadii kan sọ pe kọ́kọ́rọ́ kan ṣoṣo to si ilẹkun ẹ̀mí gigun, ni ki ọkùnrin fẹ iyawo keji.
Àwọn oluwadii ọhun ni awọn ṣe iwadii naa laarin awọn ọkunrin ti ọjọ ori wọn ti le ni ọgọ́ta, kaakiri ogoje orile-ede.
- Ilé tí mo kọ́ ni Ìlànà Omo Oòduà, mi ò lè sá kúrò níbẹ̀ - Ọ̀jọ̀gbọ́n Banji Akintoye
- Okùnrin tó bá ọmọ ọdún 16 lòpọ̀, tó tún ya fọ́tò ìhòhò rẹ̀ dèrò àtìmọ́lé l’Ogun
- Mr Macaroni, Serap, Oby Ezekwesili, Amnesty International faraya lórí Deborah tí wọ́n pa ní Sokoto lórí ẹ̀sùn pé ó sọ̀rọ̀ lódì sí Ànọ́bì
- Ìpàdé ìjọba Nàìjíríààti ASUU lórí ìyanṣẹ́lódì tún forí ṣánpọ́n
- Àwọ̀n ènìyàn rò pé wèrè, ajínigbé ni mí, àmọ́ mo ti kọ́ ilé janturu, fẹ́ ìyàwó mẹ́sàn àn , bí ọmọ 35 – Alfa to n ṣa irin ni atan
- Oloye Adeniji Ige, Mínísítà ètò ìròyìn tẹ́lẹ̀rí ní Nàìjíríà dágbére fún ayé lẹ́ni ọdún mẹ́rìndínláàdọ́rùn ún
Ohun ti wọn ṣàkíyèsí, gẹgẹ bi ileeṣẹ iroyin Fox News, ṣe sọ, ni pe ẹ̀mí wọn gùn pẹlu ìdá mejila ju ti awọn akẹgbẹ wọn to wa ni awọn orile-ede ti ko faaye gba ile olorogun.
Gẹ́gẹ́ bi iroyin naa ṣe sọ, ọsẹ to kọja ni wọn kede abọ iwadii naa, nibi ipade apero International Society for Behavioral Ecology, n'ilu New York.
Ni ti awọn obinrin, awọn oluwadii naa sọ pe riri ati titọju awọn ọmọ-ọmọ wọn, ma n fun awọn obinrin ni ẹmi gigun.
Sugbọn o yatọ si ti awọn ọkunrin.
- Ohun tí a mọ nípa ikọlù àwọn agbébọn sí ilé ìtura ní Ikorodu rèé
- Ó dàbí ẹni pé ẹ kò mọ̀ ìdí tí mo fi ń díje dupò ààrẹ, òhun rè é - Tinubu ṣàlàyé
- Ìdí mọ́kànlá nìyìí tí mo fi fẹ́ díje dupò ààrẹ ní Naijiria – Bukola Saraki
- Ìtàn àkọ̀ròyìn Al Jazeera tí wón pa ní Israel rè é
- Óṣe! ènìyàn kan kú ẹlòmíràn farapa bí ọkọ̀ ńlá ṣe jábọ́ léwọn lórí l'Eko
- Wo àwọn iṣẹ́ méje tí o lè kọ́ láàrín oṣù mẹ́ta ti ASUU da iṣẹ́ sílẹ̀
- Fífún ẹkùn tàbí ẹ̀yà kan ní tíkẹ́ẹ̀tì 'zoning' kò sí nínú òfin ẹgbẹ́ wa - PDP
Bi iyawo ti wọn fẹ ba ṣe pọ to, ni iye ọmọ ti wọn bi naa yoo ṣe pọ, nitori pe wọn ni anfaani lati bímọ titi di ọjọ ogbó.
"Jijẹ baba fun ọpọlọpọ ọmọ, jẹ idi pataki ti iru àwọn ọkùnrin bẹẹ fi ma n tiraka lati pẹ laye ju awọn to fẹ iyawo kan ṣoṣo, to si tete n dawọ ọmọ bibi duro."