You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Olawale Adeniji Ige: Mínísítà fún ètò ìròyìn tẹ́lẹ̀rí ní Nàìjíríà dágbére fún ayé lẹ́ni ọdún mẹ́rìndínláàdọ́rùn ún
Minisita naa to jẹ agba ninu ijọ Onitẹbọmi Baptist fi ọmọ mẹrin silẹ si aye lọ.
Minisita fun ọrọ iroyin tẹlẹri ni Naijiria, Olawale Adeniji Ige ti jade laye ni ẹni ọdun mẹtalelọgọrin.
Ninu atẹjade ti awọn ẹbi fi lede gba ọwọ ọmọbinrin minisita naa, Atinuke Olashore ni wọn ti kede pe Ọjọ Kẹsan an, Oṣu Karun un ni minisita naa jade laye.
- Ààrẹ Buhari pàrọwà sí ASUU láti padà sẹ́nu iṣẹ́ nítorí àwọn akẹ́kọ̀ọ́
- Ó dàbí ẹni pé ẹ kò mọ̀ ìdí tí mo fi ń díje dupò ààrẹ, òhun rè é - Tinubu ṣàlàyé
- Ìtàn àkọ̀ròyìn Al Jazeera tí wón pa ní Israel rè é
- Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ sọ̀kò pa Deborah ní Sokoto, wọ́n ní ó 'sọ̀rọ̀ òdì sí Ànọ́bì Muhammed', ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ méjì
- Wo àwọn iṣẹ́ méje tí o lè kọ́ láàrín oṣù mẹ́ta ti ASUU da iṣẹ́ sílẹ̀
- Fífún ẹkùn tàbí ẹ̀yà kan ní tíkẹ́ẹ̀tì 'zoning' kò sí nínú òfin ẹgbẹ́ wa - PDP
- Wo àwọn mínísítà ìjọba Nàìjíríà tó ti kọ̀wé fipò sílẹ̀ nítorí àṣẹ Ààrẹ Buhari
- Ìdí mọ́kànlá nìyìí tí mo fi fẹ́ díje dupò ààrẹ ní Naijiria – Bukola Saraki
- Ọ̀rọ̀ pátà dídọ̀tí tún rúná sí ìjà láàrin Nkechi Blessing àti ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ tẹ́lẹ̀, Falegan
Oloogbe naa ni adari ileeṣẹ ijọba to n risi ọrọ iroyin, ki o to da minisita ẹka naa ni ọdun 1990.
Ni ọdun 1992 ni wọn tun yan an lati ṣakoso ẹka irinna ọkọ ofurufu ati eto iroyin.
Tani Olawale Adeniji Ige to papoda?
Ọjọ Kẹtala, Oṣu Kẹwaa, ọdun 1938 ni wọn bii ni Ilu Eko, amọ ọmọ bibi Ile Seedu, Ijeru ni Ogbomosho, nipinlẹ Ọyọ ni.
To si bẹrẹ iṣẹ pẹlu ileeṣẹ iroyin Nigerian Broadcasting Corporation gẹgẹ bi amoju ẹrọ ni ọdun 1957.
Lẹyin naa lo tẹ ọkọ leti lọ si oke okun lati lọ kọ imọ Electrical Engineering si ni ọdun 1961.
Lẹyin to pada si Nigeria ni 1967 ni o bẹrẹ iṣẹ pẹlu ileeṣẹ ijọba apapọ to n risi eto iroyin ati ibanisọrọ ni Naijiria titi ti o fi di ọga patapata ni ọdun 1985.
Minisita naa to jẹ ara ijọ Baptist fi ọmọ mẹrin silẹ si aye lọ.